islamkingdomfacebook


Ewu ti o wa nibi ijade ati imura ti ko dara lori Musulumi-binrin

Ewu ti o wa nibi ijade ati imura ti ko dara lori Musulumi-binrin

8987
Eko ni soki
Olohun Oba ti ola re ga pa ase ki obinrin maa di gagaa ati idunnumo igbele won, O si kilo fun won nibi irin ohoho ati imaa din ohun fun awon okunrin ki o le je iso fun won nibi ibaje sise, ati ilewonsa nibi awon okunfa fitinati. E ri ijade ni ohoho obinrin je aburu ti yio joba lori obinrin ati awujo patapata, ohun Kankan ki yio si da abo bo obinrin ju ibihoho ati itiju re.

 

Awọn erongba lori Khutuba naa:

 

1-     Atunse awọn isesi buruku yi;

2-     Mimu awọn Musulumi-binrin wa lori itiju ati piparamọ;

3-     Titi ilẹkun fitina kan ni inu ọpọlọpọ awọn fitina ti n sẹlẹ kaakiri aye loni;

4-     Ifu awọn obinrin lara aburu awọn olupepe lọ sibi ibajẹ.

 

الحمد لله الذي من رحمته أن أغلق على عباده منافذ الشر وأرخى لهم ستر الوقاية، فمن فتحها أو اخترقها وقع في الإثم والمعصية.

إذا المرء لم يلبس ثيابا من التقى

                      تجرد عريانا وإن كان كاسيا

و خير خصال المرء طاعة ربه

                     ولاخير فيمن كان لله عاصيا

وهذا الباب عند أهل العلم يسمى: "باب سد الذرائع"، ويمثل له العامة بقولهم: "الباب الذي يأتيك منه الريح سده واستريح".

Ninu ofin Shari'ah ni sise oogun abamọ pẹlu titi ilẹkun gbogbo ọna ti o le se okunfa fitina ati iwa ti ko dara. Ni inu idẹra Ọlọhun ati aanu Rẹ lori awa ẹda ni sisi ti O si gbogbo ọna oore kalẹ, ti O si ti gbogbo ọna aburu, ẹnikẹni ti o ba si si ọna aburu yii ti da ẹsẹ nla. Oju ọna yi gaan ni awọn oni mimọ n pe ni: (Saddul-dhari'ah) titi ilẹkun awọn aburu. Wọn a maa pa ni owe ni inu ede Larubawa wipe: (ilẹkun ti atẹgun ti n wa  ba ọ, ti ilẹkun naa ki o le baa ni isimi).

Nkan ti a n pe ni (dhari'ah) ni inu ede Larubawa itunmọ rẹ ni gbogbo sababi ati ọna ti o le mu eniyan de ibi nkankan ti n wa. Ti iru nkankan ti n wa naa ba jẹ anfaani kan ti shari'ah se ni ẹtọ, shari'ah yoo se ọna ti o ni ẹtọ fun iru nkan naa, sugbọn ti iru nkankan ti eniyan n wa naa ba jẹ nkankan ti shari'ah se ni eewọ, shari'ah yoo ti gbogbo ọna ti o le debi iru nkan naa pẹlu ki o se ni eewọ.

Ninu awọn nkan ti ko pamọ fun gbogbo eniyan ni aburu ti o gbale gba-oko ni asiko yi latari ijade ati imura ti ko dara rara ti ọpọ obinrin asikoyi gunle, ati ai bikita wọn lati maa si araawọn silẹ niwaju awọn ọkunrin ti ko lẹtọ ki wọn ri ihoho wọn. Bakannaa ni fifi awọn ọshọ wọn han, ni eyi ti Ọlọhun si se fifihan wọn ni eewọ ayafi fun awọn ti wọn ni ẹtọ ati rii. Dajudaju aburu nla ti ọkan kọ ni eyi, ẹsẹ ti o fi oju han ni pẹlu, ti o si tun jẹ ọkan ni inu awọn okunfa ti aluba ati iya ti o le koko latari orisisi awọn iwa agbere, iwa sina (agbere) aini itiju ati oniruuru awọn ibajẹ ti yoo maa ti ara rẹ sẹlẹ.

Ojuse ati ọranyan gbogbo Musulumi ni gbigbe ogun ti ijade ati imura ti ko dara, ki wọn ka gbogbo awọn omugọ lọwọko ni awujọ wọn ki iya ma baa sọkalẹ si tile toko.

Mo pe ẹyin ijọ Musulumi!  ẹ dunima asẹ Ọlọhun, ki ẹ se amulo awọn ẹkọ ti Ọlọhun kọ wa, ki ẹjẹki iparamọ pẹlu lilo Hijabu mọ awọn obinrin yin lara, nitori pe ohun ni okunfa imọra, ọla ati alaafia yin. Ọlọhun sọ ninu Al-kuran wipe:

{يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قل لأزواجك وبناتك ونساء الْمُؤْمِنِينَ يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِنْ جَلابِيبِهِنَّ ذَلِكَ أَدْنَى أَنْ يُعْرَفْنَ فَلا يُؤْذَيْنَ وَكَانَ اللَّهُ غَفُوراً رَحِيماً} [الأحزاب 33: 59].

"Irẹ Annabi! sọ fun awọn iyawo rẹ, ati awọn ọmọbinrin rẹ ati awọn obinrin awọn olugbagbọ ododo pata pe ki wọn fi awọn Jalbaabu (asọ ti obinrin maa n wọ leke asọ) wọn bo arawọn lati oke delẹ, eleyiun ni o sumọ lati fi mọ wọn, ki wọn ma baa ko suta ba wọn. Ọlọhun si jẹ Oluforijin Onikẹ" [Al-Ahsab 33: 59]. 'Jalaabibu' jẹ gboloun ọpọlọpọ, ti ẹyọkan rẹ jẹ: 'Jilbaab'. Ohun naa ni asọkan ti obinrin maa n daa bo araarẹ ki o le jẹ gaga ati aabo fun un. Ọlọhun pa gbogbo awọn obinrin awọn mumini lasẹ dida Jilbaab bo awọn ẹwa ati ọsọ ara wọn lati irun orii wọn, waju wọn ati gbogbo awọn ara wọn, ki wọn le baa mọ wọn pẹlu iparamọ, ki wọn si ma baa ko suta ba wọn, ki awọn naa ma se ko fitina ba awọn ọkunrin.

Nitorinaa ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin Musulumi ododo, ki ẹ ka ọwọ ibajẹ awọn alaini -laakere inu yin ko, ki ẹ se ikilọ awọn nkan ti Ọlọhun se ni eewọ fun awọn obinrin yin, ki ẹ jẹ ki wọn dunimọ lilo hijab, mo n kilọ fun yin, ẹ sọra  fun ibinu Ọlọhun ati iyaa Rẹ.Awọn ẹri ti o pọ ni o wa ninu Al-kurani Alapọnle ati sunnah Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) lori imaa pasẹ daada ati mimaa kilọ aida. Ninu awọn ẹriyi ni ọrọ ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) wipe: "Nigbati awọn eniyan ba nri nkan ti ko dara, ti wọn ko si yii pada si daada, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya Rẹ kari wọn". Ọlọhun (سبحانه تعالى) sọ wipe:

{لُعِنَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ بَنِي إِسْرائيلَ عَلَى لِسَانِ دَاوُدَ وَعِيسَى ابْنِ مَرْيَمَ ذَلِكَ بِمَا عَصَوْا وَكَانُوا يَعْتَدُونَ كَانُوا لا يَتَنَاهَوْنَ عَنْ مُنْكَرٍ فَعَلُوهُ لَبِئْسَ مَا كَانُوا يَفْعَلُونَ} [المائدة 5: 79].

"Wọn ti sẹ ibi le awọn ti wọn se keferi ninu awọn ọmọ Israil lati ori ahọn Dauda ati 'Isa ọmọ Mọriyamọ nitoripe wọn da ẹsẹ, wọn a si tun maa tayọ aala, wọn jẹ eniti kii kọ ibajẹ nigbati wọn ba see, siọ nkan ti wọn n se nisẹ" [Al-Maidah 5: 79]. Ibn Mas'ud (رضي الله عنه) sọpe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ke aayah yii, lẹyin naa ni o wa wi bayi pe: "mo fi Ẹni ti ẹmiimi n bẹ ni ọwọ Rẹ bura! Ẹ o maa paniyan lasẹ daada, ẹ o si maa sekilọ aida fun awọn eniyan, ẹ o si maa ka awọn alaigbọn lọwọ ko, ẹ o si maa duro ti ododo, ti ẹ ba kọ ti ẹ ko se bẹẹ, Ọlọhun yoo da ọkan yin kọ araayin, ti yoo si sẹ ibi leyin gẹgẹ bi O ti sẹ ibi le awọn ti o siwaju". Bakannaa ni Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) tun sọ ninu ọrọ rẹ miran pe: "Ẹnikẹni to bari nkan ti ko dara, ti ọkan kọ ki o yaa yii pada pẹlu ọwọ rẹ (gẹgẹ bii agbara tabi ipo), ti ko ba lagbara ati yii pada pẹlu ọwọ rẹ, ko yii pada pẹlu ahọn rẹ (ọrọ), ti ko ba lagbara ati yii pada pẹlu ahọn rẹ, koyi pada pẹlu ọkan rẹ (ki o fi ọkan kọ ibajẹ), sugbọn eleyi ni o lẹ ju ni igbagbọ".

Ọlọhun pa awọn obinrin lasẹ lilo hijab ti o ba shari'ah mu, ki wọn si fi idi mọ ile wọn, ki wọn ma maa jade lainidi. Bakannaa ni Ọlọhun kọ imura ati ijade ti ko dara fun wọn, ti O si kọ imaa din ohun (imaa sọrọ ifẹ)  wọn ni igbati wọn ba n ba ọkunrin ti wọn kii se elewọ wọn sọrọ, Ọlọhun se eleyi ki o le jẹ aabo fun obinrin ni, ki o si jẹ isọ fun awujọ ni apapọ, ati lati ti ilẹkun ọna ibajẹ. Ọlọhun sọ bayi pe:

{يَا نِسَاءَ النَّبِيِّ لَسْتُنَّ كَأَحَدٍ مِنَ النِّسَاءِ إِنِ اتَّقَيْتُنَّ فَلا تَخْضَعْنَ بِالْقَوْلِ فَيَطْمَعَ الَّذِي فِي قَلْبِهِ مَرَضٌ وَقُلْنَ قَوْلاً مَعْرُوفاً وَقَرْنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلا تَبَرَّجْنَ تَبَرُّجَ الْجَاهِلِيَّةِ الأُولَى وَأَقِمْنَ الصَّلاةَ وَآتِينَ الزَّكَاةَ وَأَطِعْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ} الآية [الأحزاب 33: 32].

"Mo pe ẹyin iyawo Annabi, ẹyin ko ri bii ẹnikankan ninu awọn obinrin! Ti ẹba n paya Ọlọhun ni tootọ, ẹ mase din ohun yin nigbati ẹ ba n sọrọ, nitori ki awọn ti aarẹ n bẹ ni inu ọkan wọn mọ baa mọ rankan sina (iseskuse) si yin" [Al-Ahsaab 33: 32].

Bi a bawo awọn aayah yii, a o ri wipe awọn iyawo Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti wọn jẹ iya fun awa Mumini, awọn ni Ọlọhun n pa lasẹ ki wọn lo hijab, ki wọn fi idi mọ ile wọn, ki wọn ma se din ohun wọn, ki awọn ti aarẹ ọkan n da laamu ma baa rokan sina (agbeere) si wọn, Ọlọhun pa wọn lasẹ ki wọn mọ ma jade bi awọn obinrin igba aimakan se maa n jade, ti wọn maa n fi ẹsọ ati awọn ẹwa ara wọn han, gẹgẹ bii ori, ọrun, aya, apa, ẹsẹ ati bẹẹbẹẹ lọ. Ti Ọlọhun ba wa pa awọn iyawo Annabi ti wọn jẹ iya awa Mumini ni awọn asẹ wọnyi, pẹlu ipo o wọn ati igbagbọ wọn, a jẹ wipe awa gaan ni abukaata si i julọ. Ipari ọrọ Ọlọhun yi si n tumọ si wipe gbogbo awa Mumini naa ni aayah yi n bawi. Ọlọhun sọpe:

{وَأَقِمْنَ الصَّلاةَ وَآتِينَ الزَّكَاةَ وَأَطِعْنَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ} [الأحزاب 33: 33].

"Ẹ maa gbe irun duro, ẹ maa yọ zakah ki ẹ si maa tẹle ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ" [Al-Ahsaab 33: 33]. Idi ni pe ọranyan ni awọn nkan ti Ọlọhun pa wọn lasẹẹ rẹ ni inu aayah yi jẹ fun awọn iyawo Annabi ati awọn Musulumi yoku naa.

Ọlọhun tun sọ wipe:

{وَإِذَا سَأَلْتُمُوهُنَّ مَتَاعاً فَاسْأَsلوهُنَّ مِنْ وَرَاءِ حِجَابٍ ذَلِكُمْ أَطْهَرُ لِقُلُوبِكُمْ وَقُلُوبِهِنّ} [الأحزاب 33: 53].

"Nigbati ẹ ba bi wọn ni nkan, ẹ bi wọn lẹyin gaga ni, eleyiun ni o jẹ afọmọ ọkan fun awọn ọkan yin ati awọn ọkan tiwọn naa" [Ah-Ahsaab 33: 53]. Aayah yi jẹ ẹri ti o foju han loriipe ọranyan ni ki obinrin paramọ fun awọn ọkunrin.

Hakikah (Paapa) hijab ti o ba shari'ah mu ni eyi ti awọn mọjẹmu mẹjọ ti mbọ yii pe si ara rẹ:

1-     ki hijab bo gbogbo ara ayaafi oju; nitori aayah:

{يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِنْ جَلابِيبِهِنَّ } [الأحزاب 33: 59].

suratul Al-Ahsb 33: 59: "ki wọn da Jalaabiba wọn bo ara wọn", jalibaabu si ni asọ ti o bo gbogbo ara.

2-     ki hijab gaan  ma  si   jẹ ọsọ funraarẹ; ki o ma se ni awọ orisirisi, nitoripe Ọlọhun kọ fun awọn obinrin ki wọn maa fi ọsọọ wọn han. Ti hijabu naa ba ti ni ọsọ, o di dandan ki wọn bo ohun naa.

3-     ki hijab naa jẹ asọ ti o di daada ti kii fi ara han; Abu Huraira (رضي الله عنه) sọ pe; Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) wipe: "iran meji kan n bẹ ọmọ ina ni wọn, emi o ri wọn o! iran akọkọ ni awọn ijọkan ti pasan ti o dabi iru maalu n bẹ pẹlu wọn, wọn o maa fi pasan yii lu awọn eniyan. Irankeji ni awọn obinrin kan ti wọn wọ asọ tohun ti bẹẹ naa ihooho ni wọn wa, wọn o maa mi lẹngbẹ, wọn o si maa yinrun, awọn ori wọn dabi ike ẹyin rankumi, iru awọn obinrin yii ko ni wọ alijanna, koda wọn o ti ẹ ni gbọ oorun alijannah rara, bẹẹ si ni oorun rẹ de ibusọ bayi bayi". Nipabayi, obinrin miran wa ti o wọ asọ sugbọn sibẹsibẹ ihoho naa ni o wa, nitoripe irun rẹ, apa rẹ ati ẹsẹ rẹ n han sita, iru obinrin bayi ẹni laana (ibinu) ni lọdọ Ọlọhun.

4-     ki hijab naa    fẹ daada, ki o ma fun, koma baa ma gbe aworan ara jade. Tori anfaani ti a fẹ lati ara hijab ni lati dena aburu ati ewu imura ti ko dara, asọ ti o ba fẹ nikan ni o le mu wa ri iru anfaani yii. Idi niyi ti Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) fi pa Usamat (رضي الله عنه) lasẹ ki o pa iyawo rẹ lasẹ ki o fi asọ tẹlẹ asọ rẹ ki o ma baa maa fi awọn orikerike ara rẹ han.

5-     Ki hijab naa ma jẹ eyi ti a fi turare tabi lọfinda oloorun si. Toripe ọpọ Hadiisi ni o wa lati ọdọ Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti o se jijade obinrin pẹlu turare tabi lọfinda oloorun leewọ. Ninu wọn ni ọrọ Annabi ti o wipe: "Eyikeyi obinrin ti o ba lo nkan oloorun ti o wa kọja lọdọ awọn ijọ kan , nitori ki wọn lee gbọ oorun ara rẹ, iru obinrin bẹẹ oni sina (alagbere) ni". Bakanaa Abu Huraira (رضي الله عنه) sọ fun obinrin kan ti o kọja ni ẹgbẹ rẹ, ti oorun si jade lara obinrin naa, Abu Huraira (رضي الله عنه) pe obinrin naa o si bii pe: njẹ mọsalasi ni o n lọ bi? Arabinrin naa dahun wipe: bẹẹ ni. Abu Huraira (رضي الله عنه) tun bii wipe: njẹ nitori rẹ ni o se lo lọfinda bi? O dahun wipe: bẹẹ ni. Abu Huraira (رضي الله عنه) si wi fun un pe: pada, ki o si lọọ fọ lọfinda naa. Toriwipe mo gbọ ti Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "obinrin kan ko ni lọ si mọsalasi, ki oorun lọfinda si maa run ni ara rẹ, ki Ọlọhun si tun gba irun iru obinrin bẹẹ".

6-     ki hijab naa ma jọ asọ ti a sa lẹsa fun awọn ọkunrin; nitoripe Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sẹ epe le gbogbo ọkunrin ti o maa n wọ ẹwu obinrin, ati obinrin ti o maa n wọ ẹwu ọkunrin.

7-     Ki asọ obinrin ma jọ asọ awọn keferi; nitori pe shari'ah se leewọ fun gbogbo Musulumi lọkunrin  tabi ni obinrin ki o mafi isesi jọ ti keferi, ni inu ẹsin wọn ni o, tabi ni inu awọn ọdun wọn, tabi ni ibi ọsọ ti o jẹ tiwọn nikan. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) tun sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba fi isesi jọ ijọkan, dajudaju arawọn ni o wa".

8-     ki hijab ma jẹ asọ afihan, ohun naa ni gbogbo asọ ti awọn eniyan ko mọ, ki eniyan wa wọọ nitori ki ole baa han laarin wọn.

Nitori naa, ki gbogbo Musulumi se amojuto awọn majẹmu yii ni ibi asọ awọn iyawo wọn. Ki ẹ mọ pe onikaluku yin olusọ ati alamojuto niyin, gbogboyin naa si ni wọn o bi nipa nkan ti a fun un sọ. Wo surah At-Tahrim 55: 6.

{يا أيها الذين آمنوا قوا أنفسكم وأهليكم نارا وقودها الناس والحجارة عليها ملائكة غلاظ شداد لا يعصون الله ما أمرهم ويفعلون ما يؤمرون} [التّحريم 55: 6].

Riri ara ẹni laarin ọkunrin ati obinrin jẹ okunfa fitina, bẹẹ si ni rirẹ oju nlẹ jẹ ọna ọla kuro ni ibi fitina. Wo suratul-Nur 24: 30-31.

{قُلْ لِلْمُؤْمِنِينَ يَغُضُّوا مِنْ أَبْصَارِهِمْ وَيَحْفَظُوا فُرُوجَهُمْ ذَلِكَ أَزْكَى لَهُمْ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا يَصْنَعُونَ وَقُلْ لِلْمُؤْمِنَاتِ يَغْضُضْنَ مِنْ أَبْصَارِهِنَّ وَيَحْفَظْنَ فُرُوجَهُنَّ وَلا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلاَّ مَا ظَهَرَ مِنْهَا وَلْيَضْرِبْنَ بِخُمُرِهِنَّ عَلَى جُيُوبِهِنَّ وَلا يُبْدِينَ زِينَتَهُنَّ إِلاَّ لِبُعُولَتِهِنَّ أَوْ آبَائِهِنَّ أَوْ آبَاءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ أَبْنَائِهِنَّ أَوْ أَبْنَاءِ بُعُولَتِهِنَّ أَوْ إِخْوَانِهِنَّ أَوْ بَنِي إِخْوَانِهِنَّ أَوْ بَنِي أَخَوَاتِهِنَّ أَوْ نِسَائِهِنَّ أَوْ مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُنَّ أَوِ التَّابِعِينَ غَيْرِ أُولِي الإرْبَةِ مِنَ الرِّجَالِ أَوِ الطِّفْلِ الَّذِينَ لَمْ يَظْهَرُوا عَلَى عَوْرَاتِ النِّسَاءِ وَلا يَضْرِبْنَ بِأَرْجُلِهِنَّ لِيُعْلَمَ مَا يُخْفِينَ مِنْ زِينَتِهِنَّ وَتُوبُوا إِلَى اللَّهِ جَمِيعاً أَيُّهَا الْمُؤْمِنُونَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ} [النّور 24: 30-31].

Ọlọhun pa gbogbo Musulumi lọkunrin ati lobinrin lasẹ ki wọn rẹ oju wọn silẹ, ki wọn sọ awọn abẹ wọn, ki wọn mọ se sina (agbere).

Nitori naa, ọranyan ni o jẹ lori Musulumi lọkurin ati lobinrin ki wọn tiju Ọlọhun wọn, ki wọn si pa ara wọn mọ fun Un pẹlu.

الحمد لله، والصّلاة والسّلام على رسول الله، وبعد؛ فلا يخفى ما وقع فيه النساء اليوم من التوسع في التبرج وإبداء المحاسن فوجب سد الذرائع وحسم الوسائل المفضية إلى الفساد وظهور الفواحش ومن أعظم أسباب الفساد خلوة الرجال بالنساء وسفرهم بهن من دون محرم .. وقد صح عن النبي صلى الله عليه وسلم أنه قال: "لا تسافر امرأة إلا مع ذي محرم ولا يخلون رجل بامرأة إلا ومعها ذو محرم ". وقال صلى الله عليه وسلم: "لا يخلون رجل بامرأة إلا كان الشيطان ثالثهما ". وقال صلى الله عليه وسلم : "لا يبيتن رجل عند امرأة إلا أن يكون زوجاً أو ذا محرم " رواه مسلم في صحيحه.

Isesi awọn obinrin asikoyi ko pamọ rara, ohun naa ni imura ti ko dara, eyi ti o jọ ti ẹranko, ati awọn ẹwu ti o tako ijẹ ọmọluabi, ati imaa fi awọn ẹwa ara wọn han. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم)  sọ pe: "Melomelo ni ẹniti o wọ ẹwu laye, ti o se wipe ihoho ni yoo wa ni ọjọ Alkiyamah". Ninu awọn asa buruku ti o tun gbajumọ loni ni wiwapọ okunrin ati obinrin kan ti wọn kii si se ẹlẹtọ araawọn, ati sise irin-ajo ọkunrin ati obinrin ti wọn kii se eleewọ (mahram) araawọn, bẹẹ Annabi (صلّىo الله عليه وسلّم) se ni eewọ ki obinrin se irinajo laisi eleewọ nibẹ, bẹẹ ni o see ni eewọ ki ọkunrin ati obinrin dawa laaye kan laisi eleewọ rẹ (maharam) nibẹ. Nitori naa, ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin Musulumi ododo, ki ẹ kilọ imura ati ijade ti ko dara fun awọn obinrin yin, ati imaa fi awọn ẹwa wọn han sita. Ki wọn dẹkun imaa kọse awọn keferi. Ki wọn yago fun fifi irun kun irun wọn, ati wiwọ irun oyinbo. Ki wọn fi wiwọ awọn asọ peepeepe silẹ, nitoripe ko bo ihooho wọn rara. Wo ẹda khutubah yi ni ede larubawa.

Bakannaa ni o jẹ ojuse ati ọranyan fun gbogbo awọn alasẹ, olori, ijọba ati awọn Alfa ki wọn fi ọwọ sowọpọ lati se atunse awujọ, pẹlu gbigbe ogun ti awọn iwa ibajẹ ti o gbilẹ ni awujọ; gẹgẹbi irin hoho awọn obinrin, ifi awọn ẹwa araawọn silẹ ati bẹẹbẹẹ lọ.

Mo wa pe irẹ ọmọbinrin Muslumi, iwọ ti o n jade pẹlu lọfinda, iwọ ti o n wọ hijab nitori afẹ aye yatọsi tori Ọlọhun, mo pe iwọ ti o n difunfun pẹlu ọkunrin, ti o si n se irinajo pẹlu okunrin ti kii se ọkọ rẹ tabi eleewọ (mahram) rẹ, mo pe iwọ ti o n tọ ọmọ rẹ ni titọ ẹranko… bẹru Ọlọhun, tuba lọsi ọdọ Ọlọhun, dajudaju Alaforijin ni Ọlọhun.

Ki Ọlọhun sọ awọn ọmọbinrin wa kuro nibi ete awọn ọta, ki O se wọn ni obinrin rere ti yoo yago fun ọna anu, ti yoo si maa tẹle ti Al-kuran ati Sunah, .

اللهم استر عوراتنا، وآمن روعاتنا، واحفظنا من بين أيدينا ومن خلفنا، وعن أيماننا وعن شمائلنا، ومن فوقنا، ونعوذ بك اللهم أن نُغتال من تحتنا.

سبحان ربك رب العزة عما يصفون، وسلام على المرسلين، والحمد لله رب العالمين.