Erongba Lori Khutubah Naa:
· Alaye lori pataki fifi ẹtọ musulumi si ọkan.
· Alaye kikun lori paapaa ijẹ ọmọ iya ẹsin.
· Alaye nipa pe ọmọ-iya ẹsin ni agbara ju ọmọ iya ẹjẹ lọ.
· Ikilọ nipa iyapa-ẹnu, fifọnka ati pinpinyẹlẹyẹlẹ.
الحمد لله رب العالمين، جعل المؤمنين إخوة متحابين فى الدّين، ونهاهم عن التفرق وطاعة الحاسدين والمفسدين، وأشهد أن لا إله إلاّ الله الملك الحقّ المبين، وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله الصّادق الأمينن، صلى الله عليه وعلى آله وأصحابه الذين كانوا يهدون بالحقّ وبه يعدلون، وسلّم تسليما كثيرا إلى يوم الدّين.
Ọpe ni fun Ọlọhun ọba gbogbo ẹda, Ọba ti o se gbobo Musulumi ni ọmọ iya ara wọn latari ẹsin, ti o si ko iyapa ẹnu, itẹle awọn apẹgan ẹsin ati awọn obilẹjẹ fun wọn, Mo n jẹri pe ko si ẹlomiran ti ijọsin tọ si ju Oun naa lọ, Ọba gbogbo Ọba, Ọba ododo, Ọba ti o foju han pe Ọba ni. Atipe Anọbi Muhammad ẹru Ọlọhun ni, Ojisẹ rẹ si ni, Olododo ni, ẹni ifaiyabalẹ ni. Ikẹ Ọlọhun, Ọla Ọlọhun ki o maa ba ati awọn ara ile rẹ ati awọn ti wọn baa lo igba awọn atọnisọna ati ti wọn duro tọ titi di ọjọ igbende alikiyaomọ.
· Ẹyin musulumi, Isilaamu jẹ ẹsin ti o tobi. Wọn si gbe ilana kan kalẹ fun gbogbo ẹni ti o fẹ se ẹsin naa lati maa tọọ. Ko si ohun kan ti Isilaamu ko fun ni ẹtọ rẹ. Ninu awọn ẹtọ ẹsin ni a ti ri ẹtọ ti musulumi kan jẹ musulumi keji rẹ.
· Ẹyin ẹrusin Oluwa tootọ, awọn ọmọniyan ti pọ jaburata ni ode oni de bi pe ko si aanu, ẹniyẹpẹrẹ ni awọn ọlẹ ni iwaju awọn alagbara ti awọn alaini si di ẹni abuku ni ọdọ awọn olowo.
· Ko si anu laarin awọn ọmọniyan ni ode oni bakannaa imọ ti ara-ẹni ni o gba ode kan. Ẹni amọri o baa ku ni orin ti onikaluku nkọ. Bakannaa emi si ti gun oke odo ki afara o to ja ni gbolohun ti o gbajumọ laarin ọmọniyan.
· Olowo n se ọrẹ olowo, otosi na n se ọrẹ otosi. Ara awọn ohun ti o tun se ikunwọ fun awọn isesi yii ni pe awọn eniyan ko ri ẹni si wọn ni eti kuro nibi awọn isesi wọnyi
· Awọn onimimọ gan-an ko se apọnle fun ẹnikankan ju awọn ọlọrọ lọ.
· Ijẹ ọmọ iya ẹsin ni ohun ti Oluwa pa asẹ rẹ ninu Al-kur’an. Ọpọlọpọ ninu awọn sahabe Annabi ni wọn si gba pe, bàbá ti o bi awọn ni ẹsin Isilaamu, ko si baba miran fun awọn. Ọpọlọpọ igba bakannaa ni wọn maa n fi aayah Al-kur’an pa ẹnu da ni ẹni ti n ka pe:
{إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ إِخْوَةٌ فَأَصْلِحُوا بَيْنَ أَخَوَيْكُمْ وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ (10)}.
"Ọmọ-iya ni awọn olugbagbọ ododo jẹ nitorinaa ẹ se atunse laarin awọn ọmọya yin mejeeji atipe ki ẹ paya Ọlọhun ki a le kẹẹ yin".
· Annabi (صلى الله عليه وسلم) se alaye awọn ohun ti o sẹlẹ larin awọn Al-Aosi ati Al-Khasraji (orukọ awọn idile meji ni wọn). Wọn si pada gbọ agbọye ijẹ ọmọ-iya ẹsin.
· Bakanna o salaye nipa awọn ara Mọkka (Al-Muajirun) ati awọn ara Mẹdina (Al-Ansọr) nipa ibalopọ ati ifẹ ododo ti o lọ laarin wọn. Ẹ ko le fẹẹ ri ohun ti o jọ ijọmọniyan abi ijẹ-abara ninu ajọsepọ ti o wa ni aarin wọn. Bakannaa ọkan wọn si se ọkan.
· Hadiisi Anasi bun Maalik salaye lẹkunrẹrẹ nipa isesi awọn musulumi si ara wọn. Ninu Hadiisi na ni wọn ti salaye bi Sa’d bun Rọbiu ti o jẹ ọlọrọ se pin dukia rẹ ati awọn iyawo rẹ fun AbdurRahman bun Aof. Ti AbdurRahman si yọnda awọn dukia rẹ fun ni ẹniti n se adu’a fun pe, ki oluwa fi alubarika si ohun ini rẹ.
· Ti o bari bayii, ẹ woye si ijẹ ọmọ-iya ẹsin tootọ ti awọn saabe lo larin ara wọn.
· Awọn wọnyii to n ti gbogbo ohun ti wọn se, awọn da? Won ti lọ. Eleyi n tọka si pe awa naa yio lọ ba wọn ni ọjọ-kan.
· Wọn ni okunrin kan lọ si ọdọ Asiwaju rere kan. O wipe :
Nibo ni awọn ti wọn nna owo wọn ni oru ati ọsan, ni kọkọ ati ni gbangba wa? O dahun pe: wọn ti lọ pẹlu awọn ti wọn kii tọrọ lọwọ eniyan ni lemọlemọ… (Wo: Suratu Bakọra: 272 ati 273) nibiti Ọlọhun ti rohin awọn iran mejeeji: awọn ti nna owo wọn fi saanu tọsan toru, ati awọn alaini ti wọn kii fi karahan daamu awọn olowo; eyi ti wọn ba fun wọn naa ni wọn n jẹ ki o to awọn:
لِلْفُقَرَاءِ الَّذِينَ أُحْصِرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ لَا يَسْتَطِيعُونَ ضَرْبًا فِي الْأَرْضِ يَحْسَبُهُمُ الْجَاهِلُ أَغْنِيَاءَ مِنَ التَّعَفُّفِ تَعْرِفُهُمْ بِسِيمَاهُمْ لَا يَسْأَلُونَ النَّاسَ إِلْحَافًا وَمَا تُنْفِقُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ بِهِ عَلِيمٌ (273) الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ بِاللَّيْلِ وَالنَّهَارِ سِرًّا وَعَلَانِيَةً فَلَهُمْ أَجْرُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ [البقرة : 273 ، 274]
Eleyi ni ọmọ iya ododo ti o yẹ ki awa musulumi fi maa se arikọse, ki a maa ran ara wa lọwọ lori daada, bakannaa ki a si maa se ikunwọ pataki julọ ni akoko ti o ba yẹ.
Ninu iwọ musulumi kan si ekeji ni pe ki o ni ifẹ enikeji ni titori Ọlọhun bakannaa ti yio ba si korira rẹ ki o jẹ titori Ọlọhun. Ninu Hadiisi Anasi bun Mọlik, Annabi (صلى الله عليه وسلم) wipe: awọn iroyin mẹta kan ko nii wa fun enikan bi ko se pe o ti tọ adun igbagbọ wo, ki o jẹ pe ko si eniti a nifẹ si ju Ọlọhun ati Ojise Rẹ lọ, ki o si nifẹ eniyan kan nitori Ọlọhun bakannaa ki o korira lati se keferi si Ọlọhun gẹgẹ bi o ti korira ki Ọlọhun fi ohun si inu ina.
Abu Hurairah sọ pe Annabi r wipe: awọn eniyan meje kan yio wa ni abẹ ibooji Ọlọhun ni ọjọ ti ko ni si ibooji kan afi ti Oluwa. Awọn eniyan naa ni: Imam onideede, ọdọ ti o dagba si idi ẹsin, okunrin kan ti ẹmi rẹ so pọ mọ mọsalasi, ọkunrin meji ti wọn nifẹ ara wọn nitori Ọlọhun (wọn pade ara wọn nititori Ọlọhun wọn si tu ka tori Rẹ), okunrin kan ti obinrin abiyi ati eleewọ pe (fun iyapa ti Ọlọhun), ti o ni emi n paya Ọlọhun ati ẹniti o se itọrẹ aanu ti ọwọ osi rẹ ko mọ ohun ti ọwọ ọtun na.
· Abu Huraira sọ pe Annabi wipe: okunrin kan bẹ -eniyan rẹ kan wo ni ileto kan, oluwa wa ran malaku kan si ni ẹniti n bi bayi pe; ni bo ni on-lọ? O wipe ohun fẹẹ bẹ ọmọ-iya oun kan wo ni ileto kan. O wipe: njẹ ohun kan wa ti o nfẹ ni ọdọ rẹ? O si dahun pe rara sugbọn oun fẹ bẹẹ wo nitori Ọlọhun, malaku na sọ fun un pe, emi jẹ ojisẹ Ọlọhun si ọ, ti mo si n fun ọ ni iro idunu pe o ti di ẹniti Oluwa nifẹ si gẹgẹ bi o ti nifẹ ẹni naa.
Ninu Hadiisi Muslim ati Abu Dawud, Annabi sọ pe: mo fi ẹni ti ẹmi mi nbẹ ni ọwọ rẹ bura, ẹ ko ni wọ Alujanna titi ti ẹ o fi gbagbọ, ẹ ko si ni gbagbọ titi ti ẹ o fi nifẹ araa- yin, se ki n tọka isẹ kan si yin, ti ẹ ba fi se nkan naa ẹ o di ẹ niti yoo nifẹ ara yin. Ẹ maa fọn salamọ ka laarin araayin.
Ninu ẹtọ musulumi si ọmọ-iya rẹ ni ohun ti Annabi r sọ ninu Hadiisi Abu Huraira pe, iwọ musulumi lori musulumi mẹfa ni. Wọn bere nipa awon iwọ naa. Annabi r wipe: ti musulumi ba pade musulumi, salama sii. Ti o ba pe ọ, daalohun. Ti o ba beere amọran lọwọ rẹ fun un, bakannaa ti o ba sín ti o si yin Oluwa, ki o kii, ti o ba se aisan, bẹẹwo, ti o ba ku, ripe o tẹ lee de ibi itẹ (Muslim).
Ninu iwọ musulumi ni pe a ko gbọdọ korira rẹ tabi se keeta rẹ bi o ti le wulẹ komọ nitoripe ẹmi musulumi gbọdọ ni alaafia bakannaa ki o si mọ kanga lai ro irokuro nipa musulumi kan.
Bi o ti yẹ ki musulumi ri ni pe ki ọkan rẹ mọ kanga ni igba ti o ba wa ni ori ibusun rẹ ti ko ni nkan nkan ni okan ni aida si musulumi miran.
Anasi bun Mọlik wipe Annabi sọ pe: ẹ ma korira ara yin, ẹ ma pin yẹlẹyẹlẹ,ẹ ma ro pinpin arayin, ẹ jẹ ọmọ-iya ni bi ijọsin Oluwa.
Ọtẹ ati keeta jẹ ara awọn aisan ọkan. Ti ẹru kan ba korira musuluni kan latari oore ati idẹra ti Oluwa se fun un, gẹgẹ bi ẹni ti o korira ohun ti oluwa se fun un ni.
Ẹ paya Oluwa, ki ẹ si sẹri pada lọ si ọdọ Rẹ ni ẹniti nbere lọdọ Oluwa (ẹniti n maa n pese fun ẹru Rẹ).
Ohun ti o maa n jade lẹnu awọn olugbagbọ ododo ni pe, oluwa wa se aforiji fun awa ati awon ọmọ iya wa ti o ti lọ ninu igbagbọ ki o si ma fi ikorira si igbaya wa si awon olugbagbọ, Irẹ ni Onikẹ Alaanu.(Hashiru-10)
Ninu Musnad Ahmad, Anasi wipe: awa nbẹ ni ọdọ ojisẹ Ọlọhun ni o ba sọ pe: ọkunrin kan yoo yọ si yin ninu ọmọ Alujanna. Ni okunrin yii ba yọ pẹlu pe irun agbọnrẹ nkan fun omi aluwala rẹ, o ko bata rẹ si ọwọ osi rẹ. Ni igbati o tun di ojo keji, Annabi tun sọ bi o ti sọ, okunrin yii naa ni o tun yọ. Annabi tun sọ bẹẹ lẹẹkẹta, okunrin naa ni o tun yọ. Ni igbati Annabi dide, Abdullọh bun Amri -bun-Asi tẹ le ni ẹniti o n so fun un pe, ija sẹlẹ laarin oun ati baba oun, bakannaa oun si ti bura pe oun ko nii yọju sii fun ọjọ mẹta. Ti o ba le yọnda fun mi lati duro ni ọdọ rẹ ti ọjọ yii o fi kọja. O sọ fun wipe, ko si wahala. Anasi wipe: Abdullọh sọ pe: okunrin naa sun fun gbogbo oru mẹtẹẹta lai yan naafila titi ti o fi di akoko irun Subuhi. Adbullọhi wipe oun o ri ni ẹni ti n sọrọ afi daadaa. Ni igbati ọjọ mẹta yii pe, Abdullọh wipe irẹ ẹrusin Ọlọhun, ko si ija kan laarin emi ati baba mi, koda ko si odi yiyan laarin wa, sugbọn mo gbọ ojisẹ oluwa lẹẹmẹta ni ẹni ti n wipe: ọmọ Alujanna kan yio wọle. Iwọ si ni ẹniti o wọle lẹẹmẹta naa n o si ri ọ ni ẹniti n sisẹ lọpọlọpọ. Ki ni ohun ti o n se ti Annabi fi sọ bẹẹ lẹẹmẹta. O sọ pe n o se nkankan ju ohun ti o ri yii lọ. Abdullọhi ni, ni igbati mo pa ẹyin da, o pe mi, o wipe ohun ti mo maa n se ni pe n ko kii fi nkankan bi ọtẹ ati keeta si ọkan fun ẹnikan nititori oore ti oluwa se fun un. Abdullahi ni eleyii ni ohun ti o gbe o de ipo yii, bẹẹ awa ko kapa lati se bẹẹ.
Ninu ẹtọ ati iwọ musulumi si musulumi ni riran-an-lọwọ lati gbọ gbogbo bukata rẹ, bi eniyan ba ti ni agbara mọ.
Abu Huraira sọ wipe: Annabi sọ pe: eniti o ba ko isoro kan kuro fun musulumi ninu awọn isoro ile aye oluwa yoo ko kuro fun eniyan naa awọn isoro ọjọ idajọ. Eniti o ba se idekun fun eniti ara n ni, oluwa yio se idẹkun fun oun na ni aye ati ikẹyin. Oluwa se tan lati se iranlọwọ fun ẹru kan ni iwọn igba ti ẹru naa ba n se iranlọwọ fun musulumi miran. (Muslim)
Ninu iwọ musulumi ni pe ki a ran an se boya alabosi ni abi wọn boo si.
Ojisẹ Oluwa wipe: ran ọmọ iya rẹ ti o je alabosi se tabi ẹniti wọn se abosi si, wọn wipe bawo ni a o se ran alabosi se atilẹ gbọ ẹniti wọn se abosi si? O wipe ẹ gba ni orun ọwọ mu ẹ si kọ iwa abosi fun un.
Se aranse fun musulumi ni gbogbo akoko. Bo o ni asiri kuro nibi awọn abuku tabi awọn kudiẹ kudiẹ rẹ. ki o si se amojukuro funawọn kudiẹ kudiẹ rẹ. Eleyi ni awọn iwọ ti o tobi ti a gbọdọ pe.
· Eyin ẹrusin Ọlọhun, ijẹ ọmọ iya ẹsin ni okun ti o so gbogbo musulumi papọ ti okun na ba ti ja, ẹsin yoo mẹhẹ. Oluwa wipe:
{الَّذِينَ يَحْمِلُونَ الْعَرْشَ وَمَنْ حَوْلَهُ يُسَبِّحُونَ بِحَمْدِ رَبِّهِمْ وَيُؤْمِنُونَ بِهِ وَيَسْتَغْفِرُونَ لِلَّذِينَ آَمَنُوا رَبَّنَا وَسِعْتَ كُلَّ شَيْءٍ رَحْمَةً وَعِلْمًا فَاغْفِرْ لِلَّذِينَ تَابُوا وَاتَّبَعُوا سَبِيلَكَ وَقِهِمْ عَذَابَ الْجَحِيمِ (7)}.
"Awọn ẹniti wọn gbe Al-Arasi ru ati awọn ti o wa ni agbegbe rẹ nwọn nse afọmọ pẹlu fifi ọpẹ fun Oluwa nwọn, awọn si ni igbagbọ, won si ntọrọ aforiji fun awọn ẹniti o gbagbọ lododo pe: Oluwa wa, aanu ati imọ rẹ yika ohun gbogbo, nitorinaa fi oriji awọn ẹniti nwọn ronupiwada ti nwọn si tẹ le oju ona Rẹ ki O si sọ wọn ninu ìyà (ina) Jahimi…Suratu Gafir: 7.
Bayi ni Oluwa ti tọka si okun to so awọn ti wọn gbe Al-Arasi ati awon ti n bẹ ni agbegbe rẹ papọ ati larin awọn ọmọ Adamọ de ibi pe wọn se adua banta banta yii fun wọn.
· Oluwa tọka si ohun ti o sowa papọ gẹgẹ bii igbagbọ ododo ninu Ọlọhun ọba “Allah”, nitori idi eyi a gbọdọ mọ pe ọmọ iya ni awọn onigbagbọ ododo jẹ laarin araa wa.
· Eyin onigbagbo ododo, o di ọwọ wa lati maa se ikunwọ ati iranlọwọ fun araawa ki a so araawa papọ ki a ma si pin yẹlẹyẹlẹ.
· Oluwa wipe:
وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ وَاصْبِرُوا إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِين [الأنفال : 46]
"Ẹ ma se se ariyanjiyan ki ẹ ma se ojo ki agabara yin ma baa lọ. Ki ẹ si se suuru. Dajudaju oluwa n bẹ pẹlu awọn oni suuru".
· Oluwa tun wipe:
{وَاعْتَصِمُوا بِحَبْلِ اللَّهِ جَمِيعًا وَلَا تَفَرَّقُوا
"Ẹ so araayin papọ pẹlu okun Ọlọhun ki ẹ si ma pin yẹlẹyẹlẹ".
Annabi ni e se araayin ni ẹyọ kan
· Ẹ maa paya oluwa ki ẹ si mọ pe oluwa nbẹ pẹlu akojọ. Ẹ maa gbe pẹlu awọn ọmọ iya yin ti wọn jẹ olugbagbọ ododo ni ẹniti o so papọ. Ki ẹ si ranti pe oluwa nbẹ pẹlu janmọ o si jinna si awọn ti wọn ti fọnka yẹlẹyẹlẹ.
فاتّقوا الله أيّها المسلمون وأدّوا حقوقكم تجاه إخوانكم المسلمين، ثم اعلموا –رحمكم الله- أنّ الله أمركم بالصلاة والسّلام على خير الورى فقال:{ إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيمًا}. اللهم صلّ وسلّم على عبدك ورسولك محمّد نبيّ الرّحمة والهدى. وارض اللهم عن خلفائه الأربعة أبى بكر وعمر وعثمان وعلي نجوم الدّجى وعن سائر الصحابة والتّابعين ومن سار على نهجهم واقتفى وعنّا معهم بعفوك وكرمك وإحسانك، يا خير من تجاوز وعفا.
Ẹ bẹru Ọlọhun – ẹyin olugbagbọ ododo- ki ẹ si pe iwọ yin lori awọn ọmọ iya yin Musulumi, ki ẹ si lọọ mọ pe Ọlọhun payin lasẹ titọrọ ikẹ ati igẹ fun asaaju ẹda Annabi Muhammad. Ọlọhun banikẹ ki o bani gẹ ẹ ati gbogbo awọn ara ile rẹ ati gbogbo awọn Sahabe lapapo, ati gbogbo ẹni ti o ba nrin oju ọna wọn titi di ọjọ agbende.