islamkingdomfacebook


IGBE ARA LE OLOHUN TI OLA RE GA

IGBE ARA LE OLOHUN TI OLA RE GA

4798
Eko ni soki
Igbarale Olohun Oba ti ola re ga je ohun ti a fe ti o tobi, o si je ase lati odo Olohun ti ola re ga fun awon eru re ti won je onigbagbo olodo, O si pa won lase re nibi gbogbo isesi pata. Igbarale Olohun ni ifiarati okan ti o je ti ododo le Olohun Oba ti o tobi ti o gbongbon nibi fifa daadaa ati titi aburu danu, ti o ba je wipe eru gbe ara le Olohun ni igbarale otito ni, Olohun ko ba too, ko ba si se ipese fun gegebii O ti npese fun eye ati awon eranko.
Awon Erongba Lori Khutubah naa:
1- Alaye lori (Attawakulu) ati bi o ti se Pataki to fun Musulumi lati maa gbe ara le Oluwa .
2- Alaye lori pe gbigbe ara le Oluwa jẹ koseemọni fun ini igbagbọ ododo (Iimaani).
3- Alaye lori pe lilo awọn okunfa oore ko lodi si gbigbe ara le Oluwa.
4- Siso ẹmi Musulumi pọ mọ ironukan Oluwa, atipe gbogbo ẹda patapata ni o ni bukaata si Oluwa Adẹdàá.
5- Ikilọ lori gbi ero-buburu si awọn osu tabi ọjọ kan pato, tabi nitori asa tabi ise igba aimọkán-mọkàn (jahili) ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu awọn ohun ti o lodi si gbigbe ara le Oluwa (Attawakkuul).
 
الحمد لله، خلق كل شيء فقدره تقديراً، وأجرى الأمور على ما يشاء سبحانه حكمة منه وتدبيراً، أحمده تعالى وأشكره، لم يزل بعباده لطيفاً خبيراً، وأستعينه وأستغفره وأتوكل عليه، وكفى به عليماً بصيراً، وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له؛ به المعتصم وإليه الملتجأ، وعليه التوكل، وكان الله على كل شيء قديراً، وأشهد أن نبينا محمداً عبد الله ورسوله؛ بعثه بين يدي الساعة بشيراً ونذيراً، وداعياً إلى الله بإذنه وسراجاً منيراً، صلى الله عليه وعلى آله وأصحابه أعلام الهدى، ومصابيح الدجى، ومن بهداه اهتدى، وسار على نهجه واقتفى، وسلم تسليماً كثيراً.
Wiwa jijẹ-mimu, adamọ ọmọniyan ni, sugbọn ki ẹniyan o ma se kọ lu ọgba Ọlọhun latari sise bẹẹ.
Laisi ani-ani, awọn idi pọ ti ọmoniyan yio fi maa wa arisiki. Yala lati bọ aya ati ọmọ nio, tabi lati tun ọmọluabi ẹni se, ati lati ba ẹgbẹ pe ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eleyi si lee fa ki eniyan ma bikita ibi-kibi ti owo tabi arisiki ko baa ti wa.
Isilaamu se kilọ-kilọ pe bi o ti wu ki o ri, wiwa owo ati arisiki ko gbọdọ mu ni fa ọgba ofin Ọlọhun ya.
Ojisẹ Ọlọhun r sọ bayi pe: "Iba se wipe ẹyin ngbe ara le Oluwa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ ni, Oun (Ọlọhun) ko ba pese jijẹ-mimu fun yin (ni irọrun) gẹgẹ bi O ti n se fun awọn ẹyẹ; ti wọn yoo jiijade lowurọ kutu tebi-tebi sugbọn ti won yoo si ti jẹ ajẹyo nigbati wọn o ba fi wọle sun ni asaalẹ".
 
عن عمر بن الخطاب رضي الله عنه : أن رسول الله صلى الله عليه و سلم قال : "لو أنكم توكلتم على الله حق توكله لرزقكم كما يزرق الطير تغدو خماصا و تروح بطانا". أخرجه الحاكم في المستدرك 4/354 وقال: صحيح الإسناد
Ibn Mas'ud t naa sọ pe: " Ninu ohun ti o tọka bi amọdaju eniyan ti kere to ni ki eniyan maa fi ibinu Ọlọhun wa iyọnu eniyan; ki o maa yìn awọn eniyan lori arisiki ti Ọlọhun se. Bẹẹ si ni ojukokoro olojukokoro kan ko le mu arisiki wa, atipe kikọ ti ẹnikan ba ,ko le di ọna arisiki mọ eniyan. Nipasẹ ise deede Ọlọhun Ọba ni O fi fi ibalẹ-aya ati idunnu sibi ohun ti o da eniyan loju ati ki eniyan yọnu (si ouhn ti Ọlọhun se fun un), ti O si fi aibalẹ-ọkan ati ibanujẹ sibi isiyemeji ati aidunnu (si ouhn ti Ọlọhun se).
 
Oluwa sọ pe:
وَلِلَّهِ غَيْبُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَإِلَيْهِ يُرْجَعُ الْأَمْرُ كُلُّهُ فَاعْبُدْهُ وَتَوَكَّلْ عَلَيْهِ وَمَا رَبُّكَ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُون [هود : 123]
 "Ti Ọlọhun ni ohun ti o pamọ ni sanmọ ati ilẹ, ọdọ Rẹ si ni a o dari ohun-gbogbo si. Nitorinaa jọsin fun Un ki o si gbe ara le E. Oluwa rẹ kii se alaimọ nipa ohun ti ẹ n se nisẹ" (Hud: 123).
 
Oluwa tun sọ pe:
وَتَوَكَّلْ عَلَى الْحَيِّ الَّذِي لَا يَمُوتُ وَسَبِّحْ بِحَمْدِهِ وَكَفَى بِهِ بِذُنُوبِ عِبَادِهِ خَبِيرًا [الفرقان : 58]
 "Atipe ki o gbe ara le (Ọlọhun) Alaaye Ẹni ti kii ku. Ki o si se afọmọ pẹlu ẹyìn Rẹ. Atipe Oun (Ọlọhun) to ni Arinurode nipa ẹsẹ ti awọn ẹru Rẹ nda". (Al-Furqaan: 58). Awọn aayah miran ti o tun tọka eleyi ni: As-shu'araa': 217; Al-ahsaab: 3.
Ojisẹ Ọlọhun r naa si sọ pe:
وعن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي r : "يدخل الجنة أقوام أفئدتهم مثل أفئدة الطير" رواه مسلم.
 "Awọn ijọ kan yio wọ alijannah, ọkàn wọn yio da bi ọkan ẹyẹ (nipa igbe ara le Ọlọhun).
 
Gbigbe ara le Ọlọhun jẹ ọkan pataki ninu ọna ti a le fi sun mọ Oluwa. Koda eniyan ko le jẹ onigbagbọ ododo titi yio fi ni igbe ara le Ọlọhun tootọ.
 
Awọn irohin meji ni o gbọdọ wa fun ẹni ti o n gbe ara le Ọlọhun: 1- Ki eniyan maa gbiyanju lati wa arisiki ati 2- Ki o wa a gbe ara le Oluwa Ọba ti o ni gbogbo sababi lọwọ.
Nitorinaa igbe ara le Oluwa ko tumọ si  ọlẹ tabi imẹlẹ. Bi kosepe ki a se isẹ oojọ ẹni bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, lẹhinaa ki a waa fi igbagbọ wa ti si ọdọ Ọlọhun nikan soso, pe ohun ti O ba se nikan ni yoo jẹ sise, bi o ti wu ki ẹda o sisẹ tabi laagun to.
Imọ Ọlọhun lọkan si ni agba ninu ohun tii mu eniyan maa gbe ara le Ọlọhun.
Ki eniyan tilẹ ronu sii:
Kinise ti ọmọniyan ti o mọ daju pe alaini ni oun ko see nii gbe ara le Oluwa ti o ni ohun gbogbo ni ikawọ?
Ani kini se ti ọmọniyan ti o mọ daju pe ọlẹ alai lagbara ni oun ko see ni maa wa Ọlọhun ni Oniranlọwọ, ki o si maa sẹri pada lọ ba A?        
Abi kini se ti ọmọniyan ti o mọ daju pe Ọlọhun a maa se aanu awọn ẹda Rẹ ju bi iya tii se aanu ọmọ rẹ lọ ko se nii fi ọkan balẹ si etoo Rẹ?
Ani kini se ti ọmọniyan ti o mọ daju pe Ọjọgbọn ni Ọlọhun nibi gbogbo idajọ Rẹ ko se nii dunnu si kadara Rẹ.

بارك الله لي ولكم في القرآن العظيم، ونفعني وإياكم بهدي سيد المرسلين، وثبتنا وإياكم على الصراط المستقيم، وأجارنا بمنه وكرمه ورحمته من العذاب الأليم، هذا وبعد قولي سلفاً أستغفر الله لي ولكم ولجميع المسلمين، فاستغفروه وتوبوا إليه إنه كان حليماً غفوراً

 
Ọmọniyan gbọdọ gbiyanju gẹgẹ bi a ti sọ siwaju, sugbọn ko gbọdọ gbe ara le igbiyanju araa rẹ bi ko se pe ki o gbe ara le Ọlọhun.
 
Gbigbe ara le Ọlọhun ko tako ki ẹda gbiyanju agbara rẹ. Ẹri eleyi wa ninu ọrọ Ọlọhun  ti o lọ bayi pe :  {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا خُذُوا حِذْرَكُمْ} [النساء:71]
"Ẹyin olugbagbọ ododo ẹ mu ara yin giri (nigba ti ẹ ba fẹ lọ pade ọta, ẹ ma se tura silẹ o)"
Ati ọrọ Rẹ miran ti o ni: {وَأَعِدُّوا لَهُمْ مَا اسْتَطَعْتُمْ مِنْ قُوَّةٍ} [الأنفال:60].
"Atipe ki ẹ si pese de wọn (awọn ọta) ohunkohun ti ẹ ba lagbara rẹ ni ohun ija"
Lẹhinaa ki o di amọdaju fun onikaluku wa pe: ẹnikan ko nii kuro lori ilẹ aye yii ayafi ki o ti na gbogbo ohun ti Ọlọhun pa lebubu fun un ni arisiki; nitorinaa ẹ jẹ ki a fi pẹlẹ pẹlẹ wa aye, ki a ma ba ọrun wa jẹ o.
Igba ero-buburu si awọn osu tabi ọjọ kan pato, tabi nitori asa tabi ise igba aimọkán-mọkàn (jahili) ati bẹẹ bẹẹ lọ, wa ninu awọn ohun ti o lodi si gbigbe ara le Oluwa (Attawakkulu).
Ọranyan ni ki Musulumi jinna si ohun gbogbo ti o ba lodi si gbigbe ara le Oluwa (Attawakkulu); osu, ọjọ tabi akoko kan ko le da se aburu fun eniyan tabi see ni ore, lẹhin ohun ti Ọlọhun Ọba ti kadara
Bakannaa, riri ẹyẹ tabi ẹranko kan ko nihun se pẹlu didara aye ẹda tabi buburu rẹ.
Ẹni ti a rinnako lowurọ kutukutu tabi ọjọ ti a bini waye koni ohun kohun see pẹlu rere tabi aburu ti o ba eniyan.
Ki olukuluku woye si awọn asa ati ise ti o lodi si gbigbe ara le Oluwa (Attawakkulu), koda ko baa jẹ ọrọ afi ẹnu sọ.
Gbigbe ara le Ọlọhun nikan ni oogun fun gbogbo idaamu, ibanujẹ ati aibalẹ- aya ni aye ati ọrun.
Ewe kan ko le jabọ lẹhin Ọlọhun Ọba ti O mọ ohun gbogbo.
Ọluwa nikan ni o ni imọ ikọkọ, nitorinaa iwọ Musulumi, jina tefe-tefe si gbogbo opurọ, adagbigba, aworawọ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Jinna si asa yẹmiwo, yala o fẹ rin irin ajo ni, o fẹ fẹyawo ni, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Fi ọkan rẹ tẹ Ọlọuhn nikan ki o si maa bẹ Ẹ. Ọlọhun Ọba sọ bayi pe:
{ قُلْ لا يَعْلَمُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الْغَيْبَ إِلا اللَّهُ} [النمل:65]
"Sọ pe: ko si ẹnikan ni sanma ati ilẹ ti o ni imọ ikọkọ (ohun ti yoo sẹlẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ) ayafi Ọlọhun".
Oluwa naa tun sọ wipe:
{وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلا رَادَّ لِفَضْلِهِ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ} [يونس:107]
"Atipe ti Ọlọhun ba tilẹ fi iniran kan kan ọ, ko si ẹni kan ti o le muu kuro ayafi Oun naa, ti O ba si waa gbero oore kan fun ọ , ko si ẹni kan ti o too da ọla Rẹ pada; A maa fun ẹni ti o ba wuU ninu awọn ẹrú Rẹ, atipe Oun ni Oluforijinni Alaanu julọ". (Yunus: 107)
Alistikhaarah (adua ti a maa n se lati wadi ibi ti oore wa fun eniyan ninu ohunkohun) ni ohun ti Isilaamu fi ara mọ lati se, fun ohun ti o ba runi loju, ti a ko mọ ewo ni ki a se.
وصلوا وسلّموا على خير خلق الله محمد بن عبد الله وعلى آله وصحبه أولي التوكل الصادق واليقين بالله سبحانه وتعالى.