Erongba Lori Khutuba Naa:
1- Kikọni ni suuru sise, atipe bi o ti se jẹ iwa ti a gbọdọ ba lọwọọ Musulumi.
2- Alaye lori awọn ọna ti suuru sise pin si.
3- Suuru sise nii mu ki ibagbepọ laarin awujọ di irọrun.
الحمد لله رب العالمين على فضله وإحسانه، أمر بالصبر وأثنى على الصابرين ووعدهم أجرا عظيما؛ وأشهد أن لا إله الاّ الله وحده لا شريك له وكفى بالله عليما وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله صلى الله عليه وسلّم وعل آله وأصحابه وسلّم تسليما.
Ọpẹ ni fun Ọlọhun, Ọba to da gbogbo ẹda, lori ọla ati ikẹ Rẹ lori enikọọkan wa. O pawa lase suuru sise, O si yin awọn onisuru pupọ, bẹẹni O se adehun ẹsan to tobi fun wọn. Mo jeri pe ko si ẹnikan ti ijọsin ododo tọ si ayafi Ọlọhun nikan, Ọlọhun Ọba to ni Olumọ julọ, bẹẹni mo jẹri pe Anabi wa Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ Rẹ si ni pẹlu, Ikẹ at Igẹ Ọlọhun ki o maa ba, ati awọn ara ile rẹ tofi dori awọn sahabe rẹ.
Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹ lọ mo pe suuru sise jẹ nkan pataki ti ko see fi oju yẹpẹrẹ.
Suuru sise ati aranse Ọlọhun jẹ ọmọ iya ti kii yaa araawọn. Oluwa se adehun fun awọn oni- suuru pe wọn yoo yege. Bakkannaa ko si agbara ninu iroyin ẹni ti ko ni suuru. Oluwa wipe:
{يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا اصْبِرُوا وَصَابِرُوا وَرَابِطُوا وَاتَّقُوا اللَّهَ لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُون}.
"Ẹyin ti ẹ gbagbọ! Ẹ se suuru, koda ki suuru tiyin ju ti awọn ẹlomiran lọ, ẹ duro sinsin ki ẹ si bẹru Ọlọhun ki ẹ le se oriire… "Suratul Al-Imrana 3:200)
Ẹni ti o ba pofo suuru ti pofo igbagbọ ododo nitoripe Oluwa ni:
... فَإِنْ أَصَابَهُ خَيْرٌ اطْمَأَنَّ بِهِ وَإِنْ أَصَابَتْهُ فِتْنَةٌ انْقَلَبَ عَلَى وَجْهِهِ خَسِرَ الدُّنْيَا وَالْآخِرَةَ ذَلِكَ هُوَ الْخُسْرَانُ الْمُبِينُ [الحج : 11]
"… ti nkan daadaa ba sẹlẹ si i (ọmọniyan), yoo dunnu yoo si fọkanbalẹ sii, amọ ti adanwo ba kan an, yoo pa ohun da, o (ẹni naa) ti pofo aye ati ọrun, eyiun si ni ofo ti o foju han ".
Awọn ti wọn jẹ ẹni ifọkanbalẹ laye ni awọn oni-suuru bakanna awọn ni ẹniti igbesi aye wọn yoo rọrun.
Sugbọn Oluwa wipe:
{ذَلِكَ فَضْلُ اللَّهِ يُؤْتِيهِ مَنْ يَشَاءُ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيم}.
"Oore Ọlọhun ni o, A si maa fun ẹniti o ba wu U. Oluwa jẹ Ọlọla ti o tobi".
Suuru sise jẹ ikan ninu iwa musulumi, ẹnikan ko si nii gba iroyin pẹlu rẹ ayafi ẹniti oluwa ti jogun iduro sinsin fun. Awon ojisẹ Oluwa ati awọn iransẹ rẹ ni awọn ti wọn jẹ arikọse lori iwa suuru.
Imam Ahmad (ki oluwa kẹẹ) wipe: Oluwa darukọ suuru ni ọna aadọrun ninu Al-Kur’an. Ọla ti o pọ ni mbẹ fun suuru sise ati awọn oni suuru, lara eyi ni":
· Oluwa se ẹyin fun awọn oni-suuru ninu Al-Qur’an bakanna O sise adehun pe ohun yoo san ẹsan wọn laini isiro. O wipe:
إِنَّمَا يُوَفَّى الصَّابِرُونَ أَجْرَهُمْ بِغَيْرِ حِسَابٍ [الزمر : 10]
· Oluwa tun fun wa ni iro pe Oun nbẹ pẹlu wọn, Oun yoo fi ọna mọ wọn pẹlu pe Oun yoo se aranse ti o ga fun wọn.
· Bakanna oluwa se suuru sise ni ọranyan awọn asiwaju ki wọn le ri isẹ Oluwa jẹ bi o titọ ati bi o ti yẹ. Oluwa ni:
{وَجَعَلْنَا مِنْهُمْ أَئِمَّةً يَهْدُونَ بِأَمْرِنَا لَمَّا صَبَرُوا وَكَانُوا بِآَيَاتِنَا يُوقِنُون}.
"A se ninu wọn ni asiwaju ti wọn yoo ma tọ awọn eniyan sọna, pẹlu asẹ Wa nigbati wọn ni atẹmora (suuru), bakana ti wọn si ni amọdaju nipa awọn ami Wa".
· Oluwa se suuru sise ni ohun daradara fun ẹniyowu ti o ba fi se iwa wu.
· Oluwa tun sọ ninu Al-Kur’an pe ẹni ti o ba ni suuru ati ipaya Rẹ papọ, ọwọ abi ète awon ọta ki yoo kaa bi o ti wulẹ ko mọ.
· Ọlọhun ti so suuru ati aseyọri papọ ti wọn ko si le tuka.
· Suuru sise ni ohun ti n ma n fa ki Ọlọhun nifẹ ẹru Rẹ daradara.
Ọlọhun wipe:"إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِين". "Dajudaju Ọlọhun nbẹ pẹlu awọn oni suuru".
· Oluwa se adehun oriire mẹta fun awọn onisuuru ninu Al-kur’an pe:
{وَبَشِّرِ الصَّابِرِينَ (155) الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُمْ مُصِيبَةٌ قَالُوا إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعُونَ (156) أُولَئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ وَأُولَئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ}.
"Fun awọn onisuuru ni iro idunnu. Awọn ti ma n sọ ti adanwo ba kan wọn pe ọdọ Oluwa ni ati wa, bẹẹ ọdọ Rẹ naa ni a o pada si. Awọn yẹn ni ikẹ ati igẹ oluwa yoo bo wọn daru bakannaa wọn yoo wa ninu ẹni imọna".
· Oluwa ti se adehun Alujanna fun awọn onisuuru pe Oun yoo bọ okun ina kuro ni ọrun wọn.
· Suuru sise je jíja ẹmi ara ẹni lógun kuro ni bi ibinu.
· Suuru sise jẹ kikapa ahọn ẹni kuro nibi isọkusọ.
· Suuru sise nii jẹ ki ẹru kapa ara rẹ kuro nibi nina ara ẹni ati fifa asọ ya mọ ara ẹni lara ni igba ti adanwo ba de.
· Ni kukuru, suru sise jẹ nini ifarada lori ohun-kohun ti o ba kan ọmọniyan ninu musiba.
Bakana ki a si mọ wipe Oluwa nikan ni a ma n keepe ni igba idẹra ati igba isoro. Nitoripe kikepe ẹda Ọlọhun ni igba kuugba jẹ ise aigbagbọ ninu Oluwa ati pe ẹni ti a tun n pe ko le dahun ibeere bi kii sepe yoo ma se alekun isoro ni. Ọdọ oluwa ni a ma n gbe isoro lọ.
Suuru pin si ọna mẹta ọtọọtọ
Alakọkọ: Sise suuru lori awọn asẹ Oluwa lati le mu wa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.
Ẹlẹẹkeji: Sise suuru kuro ni bi awọn nkan ti oluwa kọ fun wa.
Ẹlẹẹkẹta: Sise suuru lori awọn akọọlẹ oluwa lori gbogbo nkan pata.
Lori awọn nkan mẹtẹta yii ni Alfa Agba Sheik Abdul-Kọọdiri (Al-Jilani) ti wipe: ko si bi o ti wulẹ ki o ri, ẹru gbọdọ tẹ le asẹ Ọlọhun, jina si awọn eewọ Rẹ, ati ki o ni igbagbọ si kadara.
Bakanna ni Lukman sọ asọlẹ awọn nkan mẹta yii fun ọmọ rẹ pe: irẹ ọmọ mi, maa ki irun, maa pasẹ daadaa ki o si kọ iwa ibajẹ bakanna ki o ni atẹmọra lori ohun ti o ba kan ọ.
يَا بُنَيَّ أَقِمِ الصَّلَاةَ وَأْمُرْ بِالْمَعْرُوفِ وَانْهَ عَنِ الْمُنْكَرِ وَاصْبِرْ عَلَى مَا أَصَابَكَ [لقمان : 17]
Musulumi ko gbọdọ maa tanmọ adanwo bakanna o gbọdọ maa se suuru lori ohun ti o ba baa ninu adanwo gẹgẹ bi o ti wa ninu Hadiisi Abdullah bn Abi Aofa.
Annabi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa baa) ti kọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ lati maa rankan adanwo nitoripe ko si ẹni ti o mọ ninu wọn boya oun yoo le se suuru tabi yege nibi adanwo naa.
· Oluwa ati Anaabi Rẹ gbawa niyanju lori pe ki a se suuru bakannaa ki a ma se kanju gẹgẹ bi o ti wa ninu Hadiisi Khabaab ibn-l-Arati pe: Oluwa yoo dahun awọn ibeere wa ni iwọn igba ti a ko ba ti kanju.
· Ọmọniyan ni lati maa se suuru titi di ọjọ iku bakannaa ki o yọnu si kadara lori gbogbo nkan.
· Ẹniyowu ti adanwo ba sẹlẹ si, ti o si tẹ le asẹ Oluwa ti o pawa lasẹ suuru, Oluwa yoo fi Oun ti o dara ju ohun ti o gba ni ọwọ rẹ rọpo fun un. Eleyi wa ninu Hadiisi Ummu Sulamah.
· Eniti Ọlọhun ba fẹ yoo danwo pẹlu orisirisi awọn adanwo.
· Adanwo jẹ nkan ti maa n pa ẹsẹ ọmọniyan ti o ba jẹ Musulumi rere rẹ.
Abu Musa wipe: Anaabi (صلى الله عليه وسلم) sọ pe: ti ijọsin ba dinku fun ẹru kan nipa aisan abi irin ajo wọn yoo maa kọọ silẹ fun pe o tun se iru ijọsin ti o maa n se tẹlẹ.
Ni igbati aisan se Abu Bakari (ki Oluwa yọnu si) awọn eniyan kan lọ bẹẹ wo. Wọn sọ fun un pe se ki a pe olùwòsàn (Dokita)? O dahun wipe: Olùwòsàn (tootọ tii se Ọlọhun Ọba) ti ri mi. Wọn bii lere pe ki ni o waa wi, Abubakri dahun pe: O sọ fun mi pe "Emi ni a se eyi to ba wuU".
Suuru sise lọdọ awọn ara ati alasunmo yoo maa kọdi awọn suta wọn si ọ.
Suuru ti ọkunrin ba se fun iyawo rẹ lori awọn asise rẹ, Ọlọhun yoo maa fi laa kuro nibi aburu rẹ.
Bakanna suuru ti iyawo naa ba se lori awọn aburu ọwọ ọkọ rẹ ni yoo se sababi oriire rẹ.
Ọga gbọdọ se suuru fun awọn osisẹ ti n bẹ ni abẹ ẹ rẹ. Ko gbọdọ se bi o ti to, bẹẹni ki o maa ranti pe enikan ni o ko wọn si abẹ oun bakanna Ẹni naa si ga ju oun lọ
Ki Oluwa se itọnisọna emi ati ẹyin naa ki o ka wa mọ ara awọn ti yoo le maa se suuru bakanna ki o ma gbe ohun ti o le ju wa lọ kawa ni aya, ki o sise wa ni ọmọ Alujannah.
فاتقوا الله عباد الله واصبروا على ما ينالكم فى هذه الدنيا من خير وشرّ فإنّ الإمامة فى الدين لا ينال إلاّ بالصّبر واليقين، اللهم اجعلنا عند البلاء من الصّابرين وعند النعماء من الشّاكرين. وصلّوا على الشّفيع المشفّع يوم الحساب فقد أمركم الله بذلك فى محكم الكتاب: {إنّ الله وملائكته يصلّون على النّبي يأيّها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما}.
Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin Musulumi, ki ẹ si se ifarada lori gbogbo ohun ti o ba n sẹlẹ siyin loore ati ni aida. Toripe onisuru nii jọba lawusa, suuru la fi n se asiwaju nidi ẹsin. A n tọrọ lọdọ Ọlọhun, ki O se wa ni eniti yio le se suuru nigbati adanwo ba de, ti yio si lee maa dupẹ lori oore Ọlọhun. Ẹ jẹ ka tọrọ ikẹ ati igẹ Ọlọhun fun Olusipẹ wa Anabi Muhammad gẹgẹ bi Ọlọhun se pasẹ rẹ ninu tira Rẹ pe : « Dajudaju Ọlọhun ati awọn Malaika Rẹ n fi ibukun fun Annabi, ẹyin ti ẹ gbagbo ni ododo, ẹ maa tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si kii ni kiki alaafia ».