islamkingdomfacebook


IKOFUNNI NIPA ADADAALE(BIDAH)

IKOFUNNI NIPA ADADAALE(BIDAH)

3519
Eko ni soki
Olohun ran anabi Muhammad(Ki ike ati ola Olohun maa baa) ni ise si gbogbo eda patapata, o si muu ise Oluwa re de ogongo, o si pee gbabamifipamo esin, o si fi awon ijo re sile lori ojuona tooto ti o funfun gboo, oru re da gegebi osan re, beeni anabi ko kuu ayafi nigbati esin ti pee ti iranse naa si ti pari, bakannaa ni anabi ko fi aaye sile fun enikeni leyin re lati fikun esin tabi dinku, bikosepe anabi lewa sa kuro nibi sise bee, ko si gbaa eyikeyi ise ti o yato si imona ati isesi re, gbogbo oore ni o wa nibi itele onaamo re, gbogbo aburu lo si wa nibi ijinna si onaamo re.

 

Erongba lori Khutuba naa:

·        Alaye nipa sùtá ti adadalẹ yoo koba ẹsin.

·        Ikọfun eniyan nipa adadalẹ ninu isẹ.

·        Alaye nipa awọn idi ti on fa adadaalẹ ninu ẹsin.

الحمد لله الذى أ مرنا باتباع رسوله وسلوك سبيله وأمرنا بالاتباع ونهانا عن الابتداع، فقال سبحانه وتعالى: {اتّبعوا ما أنزل إليكم من رّبّكم ولا تتّبعوا من دونه أولياء} وأشهد أن لا إله إلا الله، لا يقبل من الأعمال إلاّ ما شرعه، وكان خالصا لوجهه وأشهد أنّ محمّدا عبده ورسوله حذّر من البدع فقال:"وإياكم ومحدثات الأمور فإن كل بدعة ضلالة" صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه ومن تمسّك بسنته ولم يحدث فى الدّين ما ليس منه وسلّم تسليما كثيرا.

          Ọpẹ ni fun lọhun, ba to pani lasẹ itẹle ojisẹ Rẹ to si le wa jinna si adadaalẹ ninu ẹsin, lọhun ọba sọ pe:” Ẹ maa tẹle ohun ti wọn sokalẹ fun yin lati ọdọ Oluwa yin ki ẹ ma si tẹle alafẹhinti kan lẹyin Rẹ”. Mo jẹri pe ko si ẹlomiran ti a n jọsin ododo fun ayafi lọhun konii tẹwọ gba ise kan afi eyi ti o ba se lofin ti o si jẹ titori lọhun nikan, bẹẹni mo jẹri pe Anabi wa Muhammad ẹrusin lọhun ni ojisẹ Rẹ si ni, O wa wa ni isọra kuro nibi adadaalẹ, o si sọ pe: “Ẹ sọra fun adadaalẹ toripe adaadalẹ anù ni”, Ikẹ ati ọla lọhun ki o maa ba a ati awọn ara ilé rẹ ati awọn ẹmẹwa rẹ ati gbogbo ẹniti o ba di ilana rẹ mu sínkún titi di ọjọ igbende.

·        Ẹ paya oluwa ẹyin musulumi ki ẹ si dunimọ isẹ rere ki ẹ le baa di ẹni atẹwọ gba lọdọ lhun.

·        Ọlọhun yoo duro ti ẹniti o ba ba Oluwa duro ti yodoyindin aye kòkó itanjẹ baa, ẹyin musulumi, lhun ran ojisẹ si aye ni igba ti awọn eniyan wa ninu okunkun ti wọn n tẹ le ifẹ inu nibi irufẹ isesi bẹẹ.

·        Annabi dide ni ẹni ti n fun awọn eniyan ni iro idunu ti o si n kilọ fun wọn nipa iya ẹlẹta elero fun niti o ba yapa ilana lhun.

·        Ọlọhun Si se iranlọwọ fun un pẹlu pe o dide ni ẹni ti n jẹ isẹ ti a gbe lee lọwọ. Ti oluwa si se agbega fun ẹsin rẹ lati ọwọ Annọbi Rẹ.

·        Ojisẹ ko si fi aye silẹ ayafi pe o se alaye gbogbo ofin ẹsin lai safikun tabi fi nkankan pamo lai sọ fun awọn sahabe rẹ.

·        Anaabi kọ fun wa gidigan an nipa adadalẹ ninu ẹsin pe o ma n ko iparun ba olowo rẹ ni.

·        Isilaamu kọ fun wa nipa  orisirisi awọn ijọ ti yoo pada sẹyọ gẹgẹ bii awọn afi laakare tabi ọgbọn ori se ẹsin ati mimu awọn alaimokan ni olori. Ati mi maa tẹ le awon ti won ti lọ lori aimona.

·        Latari idi yii ni a firi ọkẹ aimoye awijare ẹri ninu Al-Kur’an ati Hadiisi bakannaa ọrọ awon asiwaju rere ti n se ikilọ nipa adadalẹ ti wọn si tọ wa si ọna ododo.

·        Oluwa ni :

{قُلْ إِنْ كُنْتُمْ تُحِبُّونَ اللَّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللَّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَحِيم}.

 « Sọ pe: Ti ẹyin ba ni ifẹ oluwa tootọ ẹ tẹ le emi (Annabi), Oluwa yoo ni ifẹ yin bakannaa yoo si se aforijin awọn ẹsẹ yin. Atipe Ọlọhun ni Olufori ẹsẹ jin ni Alaanu julọ ».

Ninu ayah miran :

{وَمَا آَتَاكُمُ الرَّسُولُ فَخُذُوهُ وَمَا نَهَاكُمْ عَنْهُ فَانْتَهُوا                    

« Ohunkohun ti Anaabi ba fun yin, ẹ gbaa mu gidi, ohunkohun ti o ba kọ fun yin ki ẹ jinna sii ».

·        Ko si ku nkankan lẹyin itẹle ojisẹ mo ju ifẹ inu lọ. Oluwa wipe irẹ ojisẹ mi : ti won ba kọ etiikun si ọ, ni amọdaju pe ifẹnu ni won yoo maa tẹ le,ko si ẹni ti o fin n sọnu to ẹni ti n tẹ le ifẹ inu.

·        Awon olutẹle ifẹẹnu ti sọnu kuro ni oju ọna Sunnah. Oluwa wipe:

{وَمَنْ أَعْرَضَ عَنْ ذِكْرِي فَإِنَّ لَهُ مَعِيشَةً ضَنْكًا وَنَحْشُرُهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ أَعْمَى}.

“Ẹni ti o ba gunri kuro nibi iranti Mi, daju-daju igbesi aye ti o nira yoo jẹ tirẹ, bakanna yoo wa ni ara awọn ti wọn yoo gbe dide ni afọju ni ọjọ Agbende”.

·        Eniti o ba tẹ le ọna Sunnah Anabi r  naa, ko ni sọnu bakana ko si ni jẹka.

·        Aisha (ki oluwa ko yọnu sii) sọ pe Anaabi (صلى الله عليه وسلم) sọ pe: eniti o ba mu nkan kan wa ti ko si ni ara ẹsin wa, a o daa pada sọdọ rẹ.

·        Jaabir (t) sọ pe: Annabi jẹ ẹni ti oju rẹ ma n pn ti ohun rẹ si ma n lọ soke ti o ba n se khutuba, ti yoo si fi ibinu han gidi bi ẹni ti n dari ogun, yoo si ma wipe:

 ( أما بعد فإن خير الحديث كتاب الله وخير الهدي هدي محمد وشر الأمور محدثاتها وكل بدعة ضلالة...) رواه مسلم وابن ماجه وغيرهما.

 

"Iwe tofi dara ju ni Al-kur’an, oju ọna tosi dara ju lati tọ ni oju ọna Anaabi (SAW). Eyi ti o fi n buru ju ni awọn adadalẹ, atiwipe  gbogbo adadalẹ  ọna anu ni."

·        Ẹni ti o ba kọ yìn si isesi mi ki i se ọmọ ijọ mi…Hadiisi Anasi

·        Anas Ibn Maalik wipe : Anaabi wipe : oluwa kọ lati gba “Tuuba” oni bid’a ti yoo fi gbe adadalẹ rẹ ju silẹ.

·        Abdullahi Ibn Umar wipe: Anaabi wipe: Didunnimọ Sunnah Anaabi (صلى الله عليه وسلم) ni okunfa orire fun ọmọniyan.

·        A si gbọdọ takete si awon ohun ti o ba kọ fun waa  ki a ma de bẹ.

·        Bakannaa, a kii sunmọ oluwa wa pẹlu awon ohun ti ko se ni ofin fun wa.

·        Ẹniyowu ti o ba se ijọsin kan tayọ bi Ojisẹ Oluwa r ti se yoo kabamọ ni ọjọ ẹsan. Oluwa ni : أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ شَرَعُوا لَهُمْ مِنَ الدِّينِ مَا لَمْ يَأْذَنْ بِهِ اللَّه [الشورى : 21]

 

 

« Abi wọn ni ẹnikan ti n se ofin ẹsin fun wọn lai si iyọnda Oluwa nibẹ ni bi? »

Ako gbọdọ tẹle ẹni ti ọrọ rẹ yapa awọn Sunnah ti Ọlọhun ati Annabi bi o ti wulẹ ki ẹni ti o sọ ọrọ naa ti tobi to.

Nitoripe ko si ẹni ti a ko le ba asiwi ninu ọrọ rẹ ayafi Annabi (صلى الله عليه وسلم) gẹgẹ bi Imam Maliki ti sọ (ki oluwa bani kẹẹ).

·        Awọn onimimọ rọ gbogbo ọmọniyan ti n se Sunnah lati má gbe e ju silẹ nitori ọrọ ẹnikan.

·        Imam Ahmad (ki Oluwa kẹẹ) wipe : Mo se eemọ nipa ẹni ti o mọ amọdaju nipa ẹsin ti o tun wa pada n tẹle awon olurori se ẹsin. Ti Oluwa si ti  wipe :

{فَلْيَحْذَرِ الَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنْ أَمْرِهِ أَنْ تُصِيبَهُمْ فِتْنَةٌ أَوْ يُصِيبَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ}.

«Ẹjẹ ki won sọ rase o, awon ti wọn yapa asẹ  rẹ (Annnabi r), laijẹbẹ adanwo yoo mu wọn daru, tabi ki iya ẹlẹta elero jẹ wọn ». Njẹ ẹyin mọ ohun to n jẹ Adanwo? Ohun to n jẹ adanwo na ni ẹbọ sise …".

 

Ẹyin olugbagbọ lọkunrin ati lobirin, ohun to n jẹ Isilaamu ni rirẹ ara ẹni ni lẹ fun Oluwa ati titẹle asẹ Rẹ ati mi maa se rere. Oluwa ni:

{وَمَا كَانَ لِمُؤْمِنٍ وَلَا مُؤْمِنَةٍ إِذَا قَضَى اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَمْرًا أَنْ يَكُونَ لَهُمُ الْخِيَرَةُ مِنْ أَمْرِهِمْ وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ فَقَدْ ضَلَّ ضَلَالًا مُبِينًا}.

"Atipe ko tọ fun olugbagbọ lọkunrin abi lobirin lati maa sa ẹsa nibi awọn ọrọ wọn lẹhin ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ba ti se idajọ. Ẹniyowu ti o ba yapa asẹ Oluwa ati Ojisẹ Rẹ, ẹni naa ti sọnu ni sisọnu ti o han”.

 

Nitorina ẹ tọ oju-ọna tootọ nitoripe ẹniti o ba rin ọna naa tootọ pelu ipaya Oluwa. Oluwa yoo ha awon ẹsẹ rẹ danu kuro fun.

·        Ipaya ofin ẹsin jẹ mimu oju ọna naa pọn nitoripe Oluwa sọ ninu Al-kur’an pe: وَأَنَّ هَذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيمًا فَاتَّبِعُوهُ وَلَا تَتَّبِعُوا السُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمْ عَنْ سَبِيلِه [الأنعام : 153]

 

"Eleyi ni ọna mi ti o tọ taara, nitorinaa ki ẹ tẹlee, ki ẹ si ma se tẹle awọn orisirisi oju ọna, ki ẹ ma baa sọnu kuro ni oju ọna Rẹ.

 

Oluwa kọ fun wa nipa mimu if-inu ni oludari wa. Alfa agba ti n jẹ Shatibi wipe : ẹniti o ba n da tuntun silẹ ninu ẹsin yoo pada di ẹni yẹpẹrẹ laye bakannaa yoo tun kan ibinu oluwa ni ọjọ ẹsan.

 

Ibn Abbas (ki Oluwa yọnu si) wipe : Ẹniti o ba fi irori se nkankan ninu Al-kuran ti o si tako bi Anaabi r se se alaye rẹ yoo pade Oluwa ni ẹni ti N binu sii.

Bakana ẹniyowu ti o ba da adadalẹ kan si lẹ ti o tun wa ri pe adadalẹ naa da, irufẹ enibẹ n jẹ ka mo pe Annabi ko jisẹ ti oluwa ran pe ni.

·        Oluwa ni : ni oni mo ti pe ẹsin yin fun yin. Eyi ti ko ba ti wa ni ara ẹsin ni ijọ naa, ko nii wa ni ara ẹsin ni akokoyi.

Bakana ki a lọ gba pe, ti a ba ti gbe adadalẹ kan de, oluwa yoo si mun sunnah kan kuro ni lẹ, Anaabi ni o wibẹ.

·         Ẹjẹ ki a se ohun ti o tọ, kasi jina si adadalẹ ki awon ti wọn wa ni ipo ki awọn eniyan maa tẹ le wọn, ki wọn si sọ arase. Ki a si paya oluwa wa nitoripe ibẹ ni orire wa pamọ si.

 

 

·        Ninu ohun ti a ti se ni alaye ni wipe, awọn nkan ti n se okunfa ki eniyan maaa se isẹ bid’a naa ni titẹle awn (baba) ti wn wa lori asise wn, abi fifi ara gbolẹ laitọ fun awn onimim.

·        Titẹle awon ti wn ti lọ lori asise wn ni o se okunfa sisọnu irufẹ awn eniyan kan .

·        Oluwa fun wa ni niro nipa ero awn alaigbagbọ ni igba ti Annabi Ibrahim sọ fun wọn nipa ijọsin wn si awn ẹda ọlọhun kan. Wn wipe: bayi ni ati ba awọn baba wa ti wọn nse atipe bayi ni awa naa yoo si maa se.

·        Oluwa sọ ninu Suratul Aaraf pe:

{اتَّبِعُوا مَا أُنْزِلَ إِلَيْكُمْ مِنْ رَبِّكُمْ وَلَا تَتَّبِعُوا مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ }.

 “Ẹ tẹ le ohun ti A sọkal fun yin lati ọdọ Oluwa yin, ki ẹ ma si tẹ le alafẹhinti kan lẹyin Rẹ”.

·        Ẹyin ẹrusin tootọ, awn aburu ti bid’a yoo fa pọ jaburata. Ninu wn ni:

·        Yoo maa pa Sunnah diẹ diẹ.

·        Oni bid’a yoo ma fi oju adinku wo ẹsin

·        Oni bid’a yoo ma lero pe ẹsin ododo naa ni ohun gbe dani.

·        Bid’a yoo pada sọ eniyan di alaimkan

·        Yoo si ma ri ara rẹ bi ẹniti o mọ ọna. Oluwa wipe : gbogbo ijọ ni n pe ọnaamo mọ ara wọn.

·        Bid’a yoo maa je ki eniyan se yanga si Sunnah Anaabi (صلى الله عليه وسلم)

·        Bid’a yoo si maa kọdi ẹsin ododo.

·        Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, awon saabe Anaabi jẹ ẹni ti wọn ma n kilọ lọpọlọpọ fun awon eniyan nipa adadalẹ de ibi pe Abdullah bn Moshood wọ mosalaasi ti awon oni bid’a wa.

·        Ẹyin ẹrusin oluwa ẹ paya oluwa yin ki ẹ si mọ pe ohun ti  rinlẹ lati ahọn Anaabi ni o se dandan fun yin ki e tẹ le.

·        Ẹ maa si bojuwo ohunkohun ti o ba ti yatọ si Sunnah Annabi (صلى الله عليه وسلم).

·        Oluwa yoo tọ wa si oju ọna tootọ yoo si tun fi ẹsẹ wa rinlẹ si oju ọna ẹsin rẹ (Amin).

فاتقوا الله عباد الله واحذروا البدع والمخالفات والزموا السنن واتبعوا ولا تبتدعوا. أعوذ بالله من الشّيطان الرّجيم: {وأنّ هذا صراطي مستقيما فاتّبعوه ور تتّبعوا السّبل فتفرّق بكم عن سبيله ذلكم وصّاكم به لعلّكم تتقون}.

بارك الله لي ولكم فى القرآن العظيم.

 

          Nitorinaa, Ẹ bẹru Ọlọhun ẹyin ẹrusin rẹ ki ẹ si sọra kuro nibi adadaalẹ ati iyapa ofin Ọlọhun, Ẹ dunni mọ ilana Anabi ki ẹ si tẹ lee, Ẹ ma se da adadaalẹ. Ọlọhun Ọba sọ pe :  « atipe eyi ni ọna mi ti o tọ nitorinaa ẹ te le e, ẹ ma si se tẹ le awọn ọna (miran) ki ẹ ma baa yapa kuro ni oju ọna Rẹ, eyi ni o palasẹ fun yin ki ẹ baa lee bẹru ».