islamkingdomfacebook


IRANTI OLOHUN TI OLA RE GA

IRANTI OLOHUN TI OLA RE GA

6412
Eko ni soki
Iranti Olohun(Asikiri) fun okan da gegebi omi fun eja, bawo ni eja se maa semi laisi omi? dajusaka, esin to duro deede ti gbewalongbe wipe ki musulumi maa sopo maa Oluwa re ki okan re le ba je alaaye ati lati tun maa se afomo ati imototo emi, ati lati maa

 

Awọn  erongba lori khutubah naa:

1-                 Alaye  titobi iranti  Ọlọhun ninun igbesi aye  Musulumi.

2-                 Iparọwa si Musulumi lati maa se iranti Ọlọhun ni gbogbo

igba.

3-                 Fifun ase pọ ti owa laarin ẹru ati Ẹlẹda (Ọlọhun) lagbara sii.

4-                  Wiwa isọra ti a ko ni fi wa ninu awọn ti wọn ngbagbe 

Ọlọhun.

إن قلوب البشر طُرا ، كغيرها من الكائنات الحية ، التي لا غنى لها عن أي مادة من المواد التي بها قوام الحياة والنماء ، ويتفق العقلاء جميعا ، أن القلوب قد تصدأ كما يصدأ الحديد ، وأنها تظمأ كما يظمأ الزرع ، وتجف كما يجف الضرع ؛ ولذا ، فهي تحتاج إلى تجلية وري ، يزيلان عنها الأصداء والظمأ ، والمرء في هذه الحياة ، محاط بالأعداء من كل جانب ؛ نفسه الأمارة بالسوء ، تورده موارد الهلكة ، وكذا هواه وشيطانه ، فهو بحاجة ماسة ، إلى ما يحرزه ويؤمنه ، ويسكن مخاوفه ، ويطمئن قلبه . وإن من أكثر ما يزيل تلك الأدواء ، ويحرز من الأعداء ، ذكر الله والإكثار منه لخالقها ومعبودها ؛ فهو جلاء القلوب وصقالها ، ودواؤها إذا غشيها اعتلالها .

Dajudaju ọkan ẹda ọmọniyan da gẹgẹ bi awọn ẹda miran ti o ni bukata si ohun ti yo maa fi wa laaye, ti yoo si ma fi ni idagba soke ọkan ẹda eniyan ma n dipẹta gẹgẹ  bi irin se  ma ndipẹta. Irugbin ma n ni bukata si omi ati awọn ohun ti yo yọ idipẹta kuro lara irin, ki o si fun irugbin ni ohun ti yoo jẹ ki odagba si oke. Bẹẹ gẹlẹ ni ẹmi ọmọ Annabi Aadam ni bukata si iranti Ọlọhun lọpọlọpọ, eleyi ni yoo fun ẹmi ni okun ati agbara lati koju aburu ọkan ti o npasẹ buburu, aburu shaytan  ati awọn ọmọ ogun rẹ  ati aburu ifẹẹnu.

Seikh Ibn Taimiyah sọ wipe:

قال ابن القيم رحمه الله : سمعت شيخ الإسلام ابن تيمية قدس الله روحه يقول : الذكر للقلب مثل الماء للسمك ، فكيف يكون السمك إذا فارق الماء ؟

 “Iranti Ọlọhun Pataki fun ọkan gẹgẹ bi omi se Pataki fun ẹja, bawo ni yoo se  jẹ ti ẹja ko ba ri omi?

Asepọ ẹda ọmọniyan pẹlu Ẹlẹda rẹ ko gbọdọ jẹ ni owurọ ati alẹ  nikan soso, Musulumi gbọdọ se iranti Ọlọhun rẹ ni gbogbo akoko, ni gbogbo aye  ati ni gbogbo isesi, ti yo maa tẹle asẹ  Ọlọhun, ti yo si yago fun awọn ohun ti ko gbọdọ se, eleyi jẹ afihan pe  ọmọ ẹda eniyan jẹ  ọlẹ , ni gbogbo igba ni o ni bukata si Ẹlẹda rẹ .

Islam se akole kan iranti Ọlọhun fun Musulumi lọpọlọpọ lati fi daabo bo ẹmi rẹ ki o si le fi fọọ mọ kuro ninu idọti. Ọlọhun sọ pe :

فقال عز وجل : {يا أيها الذين ءامنوا اذكروا الله ذكراً كثيراً وسبحوه بكرة وأصيلاً}.

" ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ lododo; ẹ  se  iranti Ọlọhun lọpọlọpọ, ki ẹ  si se  afọmọ Rẹ  laarọ ati irọlẹ "

 Annabi Muhammad  r sọ wipe :

وقال : (كلمتان حبيبتان إلى الرحمن خفيفتان على اللسان ، ثقيلتان في الميزان : سبحان الله وبحمده ، سبحان الله العظيم) متفق عليه .

" Ọlọhun ni ifẹ si gbolohun meji julọ, ti  o si fuyẹ  lori ahan pupọ, sugbọn ti o wuwo pupọ ninu osuwọn ise "Subhaanallahi wa bi hamdihi, sub haanallahi-l- Azeem"سبحان الله وبحمده، سبحان الله العظيم. Bukhari ati Muslim lo gba Hadith yi wa. Annabi Muhammad r sọ wipe  :

وقال : (من قال : سبحان الله وبحمده غرست له نخلة في الجنة) رواه الترمذي وحسنه الحاكم وصححه.

" ẹ ni ti o ba sọ pe : mimọ ni fun Ọlọhun Allah, ọpẹ ni fun Ọlọhun Allah, سبحان الله وبحمده ao gbin igi labidun fun iru ẹ ni  bẹẹ  lọgba Al-Jannah. (Ahmad lo gba Hadith naa wa).

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Iranti Ọlọhun lo ma n ran ni lọwọ lori awọn ajalu orisisi, Iranti Rẹ ni ọsọ, gẹgẹ bi o ti se  oju awọn ẹni gidi lọsọ pẹlu imọlẹ Hasan Basry sọ pe:

قال الحسن البصري رحمه الله : تفقدوا الحلاوة في ثلاثة أشياء : في الصلاة ، وفي الذكر ، وقراءة القرآن ، فإن وجدتم ، وإلا فاعلموا أن الباب مغلق .

"ẹ  wa igbadun si ọna mẹta: irun kiki iranti Ọlọhun ati kike  Al-Qur'an, ti ẹ  ba ri adun ni ọna mẹtẹẹta yi ẹti jere, sugbọn ti ko bari bẹẹ, ẹ  lọ ma pe ilẹkun ere ti pade mọ iru ẹni bẹẹ .

Dajudaju ọmọ Annabi Aadam ko le  se  awọn ẹsẹ  nlanla ati keekeekee ayafi akoko ti iru ẹni bẹẹ  ba fi gbagbe  Ọlọhun, tori pe iranti Ọlọhun ni kii jẹ ki ọmọ eniyan ko si inu panpẹ  ẹsẹ ti yo fi wa kọlu ibinu Ọlọhun. Ẹni ti o fi iranti Ọlọhun silẹ, oku ni iru ẹni bẹ, ti shaitan yo si ju iru ẹni bẹ  si inu akoto ẹgbin ati ẹsẹ.  Ọlọhun sọ bayi pe :

قال تعالى : {ومن يعْشُ عن ذكر الرحمن نقيض له شيطاناً فهو له قرين}.

"Ẹnikẹni ti oba fi iranti Ọlọhun silẹ esu ni yo jẹ ọrẹ  ati alajọ gbe pọ iru ẹni bẹẹ "

Iranti Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ ohun ti eniyan fi ma n jade  kuro ninu awọn munafiki, ati ninu panpẹ ifẹ inu, iranti Ọlọhun lọpọlọpọ da gẹgẹ  bi afara ti ẹru yo tọ de  ibi iyọnu Ọlọhun,

فقد ثبت عن النبي في فتح القسطنطينية : (( فإذا جاءها نزلوا ، فلم يقاتلوا بسلاح ولم يرموا بسهم ، قالوا : لا إله إلا الله والله أكبر ؛ فيسقط أحد جانبيها ، ثم يقولوا الثانية : لا إله إلا الله والله أكبر فيسقط جانبها الآخر ، ثم يقولوا الثالثة : لا إله إلا الله والله أكبر فيفرج لهم فيدخلوها فيغنموا .. الحديث )) رواه مسلم في صحيحه .

Oun ni ida si eyi ti kii saki- ti kii ku lẹnu eleyi ni ohun ti o sẹlẹ  ni asiko ti Annabi Muhammad r ati awọn sahabe  rẹ fẹ wọ Constantiniyyah Gbolohun لا اله إلا الله والله أكبر  ni wọn sọ ni ẹẹmẹta ti odi ilu na si wo lulẹ!! Muslim lo gba Hadith na wa.

Iranti Ọlọhun ni ohun ti o ni iyi julọ ti o ma n ru wuyẹ  ninu ọkan, ohun si ni o mọ julọ ninu ohun ti o njade  lati ẹnu, ohun si ni o ga julọ ninu ohun ti ete  mejeji n pe  ti o si wa ninu ọkan. Awọn eniyan n lo ọpọlọpọ igbe si aye wọn ninu pakaleke ati aiko balẹ ọkan nitoripe ko si iranti Ọlọhun ninu awọn ọkan bẹẹ. ọkan ti  iranti Ọlọhun ba joko si yo mọ titobi Ọlọhun ati wipe  Ọlọhun yi jẹ  Alagbara lori ohun gbogbo, kosi se  ẹda ohun ti agbara Rẹ  koka! Ele yi yo ko idunu ati ibalẹ  ọkan si ẹmi ẹni ti oba nrati Ọlọhun, ti orike ara rẹ  yo si balẹ  pẹlu. Ọlọhun sọ bayi pe :

                {الذين آمنوا وتطمئن قلوبهم بذكر الله ألا بذكر الله تطمئن القلوب}.

" Awọn ti wọn gba Ọlọhun gbọ ti ọkan wọn si balẹ pẹlu iranti Ọlọhun dajudaju iranti Ọlọhun ni o n fi ni lọkan balẹ ."(Suratu…..)

Iwọ ọmọ iya mi Musulumi, fi ọkan balẹ , ma se  bẹru isoro Kankan , ma se se akole ya pakaleke.. ni igba ti iranti Ọlọhun ban jẹ alabarin rẹ.

واشتكى علي وفاطمة رضي الله عنهما إلى رسول الله ، ما تواجهه من الطحن والعمل المجهد، فسألته خادما ، فقال رسول الله : (ألا أدلك على ما هو خير لك من خادم ، إذا أويتما إلى فراشكما ، فسبحا الله ثلاثا وثلاثين ، واحمداه ثلاثا وثلاثين . وكبراه أربعا وثلاثين؛ فتلك مائة على اللسان وألف في الميزان )).

فقال علي : ما تركتها بعدما سمعتها من النبي ، فقال رجل : ولا ليلة صفين ؟ قال : ولا ليلة صفين . رواه أحمد وليلة صفين : ليلة حرب ضروس دارت بينه وبين خصومه رضي الله عنهم أجمعين .

Iranti Ọlọhun yi ni Annabi Muhammad r  fi se  ẹbun ati iranti fun Fatimọh t ọmọ rẹ  nigba ti o n bere oluran lọwọ, Annabi sọ bayi fun Fatimọh ati ọkọ rẹ, ti ẹ ba fẹ  lọ si ibusun yin (ẹyin mejeji) ẹ se  (سبحان الله ) 33 ẹ se     (الحمد لله )33 ẹ se  (الله أكبر) 34 (ele yi) jẹ  ọgọrun ni sisọ, o si tẹ  iwọn ẹgbẹrun lọdọ Ọlọhun, (Ahmad lo gba Hadith naa wa) Ba yi ni Ali t ko se fi iranti Ọlọhun silẹ  ni gbobgo igbe si aye  rẹ .

Ẹgbaagbeje awọn eniyan ni wọn ti ko si panpẹ awọn oloogun, awọn babalawo ati awọn adifa. Ọpọlọpọ ni wọn nse etutu fun ajẹ , oso, awọn adaunse , Alijọnu ati opidan!! Nigba ti wọn gbe iranti Ọlọhun si ẹgbẹ kan . Se wọn ti gbagbe odi abo ti Islam tọju fun iru awọn ẹni ti n se adua bi? se wọn ko mọ pe ki a to sun bakana ti a ba ji ni adua aarọ ati irọlẹ  wa fun gbogbo Musulumi bi? Koda adura ti a ma n se  ki a to de  ọdọ iyawo wa m bẹ  pẹlu, bakana ni eyi ti a ma nse ti aba fẹ wọ ile  igbọnsẹ , tabi ti a ba fẹ  jade  kuro nibẹ . Annabi wa Muhammad r kọ wa ni orisi adua wọn yi fun aabo ati orire fun wa. Oluwa sọ wipe:

فيا أيها المسلمون اتقوا الله تعالى: {وَاذْكُرُوا اللَّهَ كَثِيرًا لَعَلَّكُمْ تُفْلِحُونَ}.

“ẹranti Ọlọhun lọpọlọpọ ki ẹ fi  le  jẹ  ere "( Surat …)

 

< face="'Times New Roman'" class="Apple-style-span">

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ọmọ eniyan ni bukata si iranti Ọlọhun ju bi o ti se ni bukata si omi ati atẹgun lọ, ti Musulumi ba mu iranti Ọlọhun ni ọkunkundun, koni si aye fun opidan, oloogun.. Oore Ọlọhun ati ọpọlọpọ alubarka yo si maa jẹ ti wa.

عباد الله : هناك من الناس من يذكرون الله ، ولكنهم لا يفقهون معنى الذكر ، فتصبح قلوبهم بعيدة عن استشعار جلال الله ، وقدره حق قدره ، وذكر الله عز وجل ، كلام تقشعر منه جلود الذين يخشون ربهم ، ثم تلين جلودهم وقلوبهم إلى ذكر الله ، غير أن الناس مما ألفوا منه ، وما جهلوا من معناه ، لا يرددونه إلا كما يرددون كلاما تقليديا

Awọn eniyan kan ko ri adun iranti Ọlọhun nitori pe wọn kọ gbọ agbọye ohun ti wọn nsọ, wọn ko si mọ itumọ ohun ti wọn npe ; wọn yo ma pe  gbolohun kan, nigba ti ọkan wọn wa ni ibomiran, daju daju ele yi kii se  iranti Ọlọhun rara. Bi a ba se  nranti Ọlọhun ninu ọkan wa, bẹẹ naani ki a se  iranti Rẹ  pẹlu ahan wa. Ọlọhun sọ wipe:

الله عز وجل : واذكر ربك في نفسك تضرعا وخيفة ودون الجهر من القول بالغدو والآصال ولا تكن من الغافلين [سورة الأعراف:205].

 " Ranti Ọlọhun rẹ ninu ọkan rẹ , ni ẹ ni ti o n tẹriba ti o si n bẹru, ati ni ohun ti ki ise  ti ariwo, ni owurọ ati asalẹ , ma sisẹ wa ninu awọn olugbagbera ("Al-a'raaf": 205.)

Ni gbogbo asiko ni iranti Ọlọhun gbọdọ jẹ, tori pe ohun ni asẹkubọ rere  fun ẹda. Ojisẹ  Ọlọhun r sọ bayi pe:

  "Ẹ mu awọn ohun isura (abo) yin! Awọn sahabe  bere  pe : ọta wo lo de ? Annabi r" sọ wipe : rara o: aabo yin ninu ina ni o,  sọ wipe  سبحان الله والحمد لله ولااله الا الله والله أكبر  yi yo wa ni ọjọ Al-qiyaamọh ti yo la wọn, ti yo si jẹ  akọkọ awọn isẹ  oloore  ẹda lọjọ naa.

Ẹni ti o n se  adua ti ọkan rẹ si ngbagbe  ko dara, tori pe anfani ti iru ẹni bẹ yo ri yo kere pupọ. Ojisẹ Ọlọhun sọ wipe :

قال رسول الله : ((اعلموا أن الله لا يقبل الدعاء من قلب لاه )) رواه الحاكم والترمذي وحسنه .

 “ẹ lọ mọ wipe  Ọlọhun ko ni gba adua ẹni ti ko si ọkan rẹ  ninu adua ti o n se  (Al- Haakam lo gba wa).

Gẹgẹ  bi ẹni ti o n wo ọtun wo osi ko ni de  ibi ti o nlọ lakoko gẹgẹ bẹ  ni ẹni ti ọkan rẹ n ya lọtọtọ lori adua ati iranti Ọlọhun.

Islam se  ni eewọ lati joko pẹlu awọn ti wọn kii ranti Ọlọhun. Annabi Muhammad r sọ Annabi Muhammad r sọ  pe awọn ti wọn kii ranti Ọlọhun, Annabi Muhammad r sọ pe:

ولذا فإن رسول الله حذر من أن تنفض المجالس دون أن يذكر الله عز وجل فيها بقوله : (( ما من قوم يقومون من مجلس لا يذكرون الله تعالى فيه إلا قاموا عن مثل جيفة حمار وكان لهم حسرة )) رواه أبو داود والحاكم .

“Ti awọn eniyan kan ba dide ni ijoko kan laiko se iranti Ọlọhun ni ijoko na, n se ni wọn yo da gẹgẹ bi ẹni ti o pejọ lori kunbete kẹtẹkẹtẹ, ti yo si jẹ adanu fun wọn. Abu Dawud ati Haakim lo gba wa.

Musulumi gbọdọ jina si ijoko irọ ijẹri-eke, eebu, epe, ati gbogbo ijoko adanu ti eniyan yo gba ẹsẹ nibẹ, ti ko ni gba laada lọdọ Ọlọhun. Iru ijoko bayi jẹ ijoko ti oti dibajẹ, eleyi Annabi Muhammad r fi sọ bayi pe:

قال صلوات الله وسلامه عليه : ((من جلس في مجلس فكثر فيه لغطه فقال قبل أن يقوم من مجلسه ذلك : سبحانك اللهم ربنا وبحمدك، أشهد أن لا إله إلا أنت ، أستغفرك وأتوب إليك . إلا كفر الله له ما كان في مجلسه ذلك )) رواه الترمذي وابن ماجة .

“ẹni ti o ba wa ni ijoko ti, won ti sọ isọkusọ ti o wa sọ gbolohun yi ki o to dide:

سبحانك اللهم وبحمدك ، أشهد أن لاإله إلا أنت، أستغفرك وأتوب إليك.

Ọlọhun yo pa awọn ẹsẹ ti o bada ninu ijoko bẹẹ rẹ (Tirmidhi ati Ibn Majah). Oluwa sọ wipe:

{يا أيها الذين ءامنوا لا تلهكم أموالكم ولا أولادكم عن ذكر الله ومن يفعل ذلك فأولئك هم الخاسرون}.  

“Ẹyin ti ẹgba Ọlọhun gbọ lododo ẹ ma se jẹ ki dukia  ati awọn  ọmọ yin di yin lọwọ iranti Ọlọhun, ẹni ti o ba se bẹẹ yọ wa ninu awọn ti wọn padanu. ( Surat …).

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون  "

اللهم إني أعوذ بك أن أشرك بك و أنا أعلم، و أستغفرك لما لا أعلم".  اللهم ارزقنا الإخلاص في القول والعمل.

اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَفِّراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاً إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ  وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَتًا مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبِّ الْعَالَمِينَ.

رَبَّنا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدَا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاتِنَا قُرَةً أَعْيُنِ وَجَعَلْنَا لِلْمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ.