islamkingdomfacebook


ISẸMI TI ỌRUN AL-KIYAMỌ LO PATAKI JULỌ

ISẸMI TI ỌRUN AL-KIYAMỌ LO PATAKI JULỌ

3187
Eko ni soki
Ninu ohun ti o ye ki musulumi gbe ola fun ni orun ti a mo si Alikiyamo je sugbon opolopo ninu awon omo eda eniyan ni o ko airoju pelu isemi aye nikan eleyii ti yio tan laisi tabisugbon, ti o ba je bee E je ki a gbe ola ati ajulo fun orun wa aaye ti a o maa wa gbere.

Awọn erongba lori Khutubah naa:

1.         Ijinlẹ Igbagbọ Al-kiyaamọ.

2.         Iparọwa lati tọju nkan fun ọrun.

3.         Ki a sọra ki a ma se tẹ si aye.

4.         Ki a mọ iyatọ laarin aye ti yoo tan, ati ọrun ti yoo wa gbere.

                   < class="Apple-style-span">

أيها المسلمون : إن مما لا شك فيه أن كل حي يعلم أن مآله إلى الموت، فالموت نهاية كل حي، {كل من عليها فان. ويبقى وجه ربك ذو الجلال والإكرام} [الرحمن 26 – 27]. إذن فللإنسان دارين، دار ممر وزوال وهو دار الدنيا، ودار مقر وخلود وهو دار الآخرة.

فالدنيا مهما طالت ومهما طال حياة من فيها فإن آخرها الزوال، فالعاقل هو الذي نظر إلى الدنيا بأنها دار تزود وزرع للآخرة التي دار الخلود.

Gbogbo eniyan ti o wa laye ni o gbọdọ mọ wipe ilé aye yoo tan, tori iku ni igbẹhin onikaluku wa. Oluwa sọ wipe:

 

" Gbogbo ohun ti o wa laye yii ni yoo tan pata ti yoo si sẹku Oluwa  Ọlọhun Allah nikan soso (Ar-Rahman 26-27) .

Ọmọ ẹda eniyan ni ilé meji: ilé ibugbakọja ti yoo tan lọjọ kan, ati ilé lailai ti ko lopin. Bi o se lewu ki aye yii ki o gun, ki o si dun fun eniyan to, yo pada tan lọjọ kan ni, oni laakaye ẹda ni ẹni ti o wo aye gẹgẹ bi ilé isẹ ti ati ma n gbin nkan ti a si maa tọju rẹ kalẹ de ilé ayeraye.

Aye jẹ ilé are, ile faari, ile ti a ti ma nfi ọpọ ọmọ, ati ọpọ owo se faari. Oluwa sọ wipe

وقال تعالى : {وما هذه الحياة الدنيا إلا لعب ولهو وإن دار الآخرة لهي الحيوان لو كانوا يعلمون} [العنكبوت : 64].

"Aye yii ko jẹ nkankan ju ilé are ọmọde ati agbalagba lọ, ilé ọrun ni yoo sẹku titi lailai ti ko si iku nibẹ, ti o ba se pe ọmọ eniyan mọ bẹẹ ni" Al-ankabuutu: 64. Aliyyu bin Abi Taalib sọ bayii - ki Oluwa ba wa yonu sii- :

وَقَالَ عَلِيُّ بْنُ أَبِي طَالِبٍ : "ارْتَحَلَتِ الدُّنْيَا مُدْبِرَةً، وَارْتَحَلَتْ الآخِرَةُ مُقْبِلَةً، وَلِكُلِّ وَاحِدَةٍ مِنْهُمَا بَنُونَ، فَكُونُوا مِنْ أَبْنَاءِ الآخِرَةِ، وَلا تَكُونُوا مِنْ أَبْنَاءِ الدُّنْيَا، فَإِنَّ الْيَوْمَ عَمَلٌ وَلا حِسَابَ، وَغَدًا حِسَابٌ وَلا عَمَل. [ذكره البخاري تعليقا].

 "Nse ni aye ma nkọyin si eniyan, ti ọrun si nkọju si eniyan, ati aye ati ọrun loni ọmọ ọtọọtọ, wa ninu awọn ọmọ ọrun, ma se wa ninu awọn ọmọ ti aye. A ni anfaani lati se isẹ ọrun laye ti a wa yii, ti isiro isẹ ko i ti de, ni ọla Al-kiyamọ a o se isiro isẹ, ko si aaye lati sisẹ lọhun.

Ẹ se alapantete ki ẹ sisẹ fun ọrun ki ẹ leri aye ati ọrun papọ, ẹ sọra ki ẹ ma se sisẹ fun aye ki ẹ ma wa padanu mejeji, aye ni ati ma nsisẹ ti a o jẹ ni ọrun, ẹni ti ko ba sisẹ fun ọrun lati aye o padanu ọrun.

Ko lẹtọ fun ọmọ eniyan onilaakaye ti o gba Ọlọhun ati Annabi Rẹ gbọ ki o le ọwọ mọ aye yii, tabi ki o mu aye ni "awaalọ", sugbọn ohun ti o yẹ fun iru eniyan bẹẹ, ni ki o maa se isẹ wipe onirin ajo ni oun, ni asiko ti a ko ro tẹlẹ ni irin ajo le tẹsiwaju. Ibn Umar sọ bayii:

قال ابن عمر : "كن في الدنيا كأنك غريب"

"wa laye gẹgẹ bi ajoji".

Isẹmi ọrun ni ko lopin, gbogbo ohun ti ọkan ba nfẹ ni yoo maa ri nibẹ, o jẹ ile alaafia ti ko ni adanwo, arun, tabi iku, ẹni ba wọ ibẹ ko nii di arugbo, ko si ni se ori buruku, Annabi r sọ wipe:

يقول النبي : "لموضع سوط أحدكم في الجنة خير من الدنيا وما فيها}

 aaye kekere kan ti a le fi pọpa si, ni inu ile Aljannah dara ju gbogbo aye ati ohun ti o wa nibẹ lọ.

 Nigbati ọrọ ri bayii, bawo ni àyè naa yoo se fẹ to, fun ẹni ti o ba wa nibẹ, Oluwa sọ bayii

يقول الله تعالى في وصف أهل الجنة وما هم فيه من النعيم : {فأما إن كان من المقربين. فروح وريحان وجنت نعيم} [الواقعة : 88 – 89].

"Awọn ti wọn sun ma wa, afẹfẹ alaafia, igbadun ati aljannah onidẹra ni yoo wa fun wọn."

 

Awọn eniyan gidi ti wọn saaju wa sọ bayii

أيها الناس لما كانت الحياة الآخرة هي الحياة الحقيقية الخالدة، جعل السلف الصالح الدنيا مزرعة للآخرة

وقال عمر بن عبد العزيز في خطبته : "إن الدنيا ليست بدار قراركم، كتب الله عليها الفناء، وكتب الله على أهلها منها الظعن، فكم من عامر موثق عن قليل يخرب، وكم من مقيم مغتبط عما قليل يظعن، فأحسنوا رحمكم الله منها الرحلة بأحسن مابحضرتكم من النقلة، وتزودوا فإن خير الزاد التقوي" [جامع العلوم والحكم 2/415] تحقيق طارق عوض الله.].

Umar bin AbdulAzeez: "Ayé kii se ilé ifarabalẹ yin, tori pe Oluwa se aye ni ohun ti yoo tan, o si ni ki ẹ lo asiko diẹ nibẹ, ẹniti o n ko nkan jọ laye ti yoo si kuro laipẹ! Se ẹ ripe o padanu? Ipalẹmọ irinajo yin ni ki ẹ mu oju to, ki ẹ si tọju ohun ti o dara fun ọrun iyẹn ni ipaya Ọlọhun.

"Yahya bin Mu'adh :sọ bayii:

وقال يحيى بن معاذ الرازي "الدنيا خمر الشيطان، من سكر منها لم يفق إلا في عسكر الموت، نادما مع الخاسرين".

Aye da gẹgẹ bi ọti èsù, ẹni ba ti mu un pupọ ko ni mọ ohun ti o nse, o di igba ti o ba ku ki o ju rẹ to la, ti yoo wa maa kabama.

Muhammad bin wasi: Ma dagbere fun awọn ara ilé rẹ ti o ba fẹ sun lalẹ pe:

وكان محمد بن واسع إذا أراد أن ينام قال لأهله : أستودعكم الله فلعلها أن تكون منيتي لا أقوم منها، فكان هذا دأبه إذا أراد النوم.

ọdigba ose ẹyin ẹbi mi, boya ao ni pade mo lẹhin ti alẹ yii.

Bakr Almuzny :

وقال بكر المزني : إن استطاع أحدكم أن لا يبيت إلا وعهده عند رأسه مكتوب فليفعل، فإنه لا يدري لعله أن يبيت في أهل الدنيا ويصبح في أهل الآخرة.

Ti ẹ ba sun lalẹ, ẹ ri aridaju pe akọsilẹ awọn Amanah (nkan oninkan ti o wa lọwọ yin wa ni kikọ ni igberi yin, ko si ẹni ti o mọ boya ti a ba sun lalẹ, a o ja si ọrun ni owurọ ọjọ keji.

Tani ko fẹẹ wa ninu oloriire aye ati ọrun? Tani ẹni ti o fẹ ni ile gagara ti o dara laye sugbọn ti ko nii ni ile kankan lọrun Alkiyamọ? Tani ko fẹ wa ninu ọmọ Aljanah lọrun? Ẹ jẹ ki a tuba siwaju Ọlọhun ninu awọn ẹsẹ wa ki a si moju to awọn asẹ Ọlọhun ki a si jinna si awọn ohun ti Ọlọhun ko fẹ. Ọlọhun sọ bayii:

قال تعالى : {من عمل صالحا من ذكر أو أنثى وهو مؤمن فلنحيينة حياة طيبة ولنجزينهم أجرهم بأحسن ما كانوا يعملون} [النحل : 97].

" Ẹni ba se isẹ daradara lọkunrin tabi lobinrin ti o jẹ ẹni ti o gba Ọlọhun gbọ, yoo gbadun isẹmi rẹ laye, a o tun wa san lẹsan eyi ti o dara ju eyiti o se laye yii lọ "Nahl" 97."

Jọwọ lo asiko ti o ku ninu igbesi aye re daradara, tẹle asẹ Ọlọhun gẹgẹ bi: irun kiki, awẹ gbigba, sara sise, sise dara dara si awọn obi, ati nina owo si oju ona ti Ọlọhun, Oluwa sọ wipe:

{وأنفقوا من ما رزقناكم من قبل أن يأتي أحدكم الموت فيقول رب لولا أخرتني إلى أجل قريب فأصدق وأكن من الصالحين. ولن يؤخر الله نفسا إذا جاء أجلها والله خبير بما تعملون} [المنافقون : 10 –  11].

"Ẹ na ohun ti a se fun yin ki iku to de, ti ọmọ eniyan yoo maa wa sọ wipe: iwọ Ọlọhun, si lọmi lara diẹ si! maa se saara, maa si di eniyan rere !, ọrọ kori bẹẹ, Oluwa ki yoo lọ ẹda kankan lara ti akoko rẹ ba ti to, ti Ọlọhun yoo si fun onikaluku niro ohun ti o gbe ilé aye se. (Al- munafikunu: 10-11)

هذا، قال الله تعالى : "إِنَّ اللهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيْتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغِيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللهِ إِذَا عَهَدْتُمْ وَلاَتَنْقُضُوا الْأَيْمَنَ بَعْدَ تَوْكَيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللهُ عَلَيكُمْ كَفِيلاً إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونٍَ"

اللَّهُمَّ أّرِنَا الْحَقَّ حَقًا، وَارْزُقْنَا اتِّبَاعَه، وَأَرِنَا الْبَاطِلَ بَاطِلاً ، وَارْزَقْنَا اجْتِنَابَه.

اللَّهُمَّ وَلِّ أُمُورَنَا خِيَارَنَا، وَلاَ تُوَلِّ أُمُورَنَا شِرَارَنَا، اللَّهُمَّ اصْلِحْ وُلاَةَ أُمُورَنَا، وَلاَ تُوَلِّ عَلَيْنَا بِذُنُوبِنَا مَنْ لاَ يَخَافُكَ فِيْنَا وَلاَ يَرْحَمُنَا. اللَّهُمَّ اغْفِرْ جَمِيعَ أَمْوَاتِ الْمُسْلِمِينَ الَّذِينَ شَهِدُوا لَكَ بِالْوَحْدَانِيَةِ وَبِنَبِيِّكَ بِالرِّسَالَةِ وَمَاتُوا عَلَى ذَلِكَ. اللَّهُمَّ اغْفِرْلَهُمْ وَارْحَمُهُمْ وَاعَفْ عَنْهَمْ وَاكْرِمْ نُزُلَهُمْ، وَوَسِّعْ مُدْخَلَهُمْ وَاغْسِلْهُمْ بِاْلَماَءِ وَالثَّلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِمْ مِنَ الُّذنُوبِ وَالْخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ وَارْحَمْنَا اللَّهُمَّ إِذّا صِرْنَا إِلَى مَا صَارُوا إِلَيْهِ بِرَحْمَتِكَ يَا أَرْحَمَ الرَّاحِمِينَ.