Erongba Lori Khutuba
· Iwosan kuro nibi iwa aburu yii.
· Titọ ẹniyan bi a ti n ni ọkan ti o ni alaafia (ti ko nii maa ro irokuro si ẹnikẹni).
· Bi ijẹ ọmọ iya ẹsin yoo se duro tọ.
الحمد لله رب العالمين حرم أذية المسلمين والتعدى على حرماتهم وتوعد من فعل ذلك بأشدّ الوعيد، أحمده عل نعمه وقد وعد الشاّكر بالمزيد، وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له وأشهد أن محمدا عبده ورسوله والقائل: "إيّاكم والظن فإنّ الظنّ أكذب الحديث". صلى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا.
A dupẹ fun Ọlọhun, Ọba ti o se sise Musulumi ni suta ati ikọja aala le lori leewọ, to si leri leka iya to lagbara fun ẹni ti o ba kọti ọgbọin si asẹ yii, A n dupẹ lori ọpọlọpọ idẹra Rẹ lori wa, ki o le salekun rẹ fun wa, A si n jẹri ajẹdẹkan pe ko si ẹlomiran ti o lẹtọ si ijọsin lododo lẹyin “Allah” , Ọba ti ko ni orogun ati pe “Annọbi Muhammad” r ẹru Rẹ ni, ojisẹ Rẹ si ni, ẹni ti o sọ ninu ọrọ rẹ pe: “:Ẹ sọra fun ero buruku erokero nitoripe erokero iro n la ni”. Ikẹ Ọlọhun, , Ola Ọlọhun, ki o maa baa, ati gbogbo awọn ara ile rẹ ati gbogbo awọn alabarin rẹ ni yanturu.
O ti di dandan lori gbogbo musulumi lati jẹ ki ajọ-sepọ ti o wa laarin awa ati awọn ọmọ iya wa yoku ti o jẹ musulimi mu ina doko
Ninu ibalopọ ti o yanranti ni ki a jẹ ki ẹmi ati ọkan wa mọ si ara wa lai sẹku nkankan ninu wa ti ko dara si ọmọ nikeji wa.
Ki a se ọkan wa daada si ọmọnikeji wa nipa erongba wa sii, jẹ nkan pataki ninu ẹsin Isilaamu.
Ki oju wa ma yatọ si ọkan wa. Ki a tu ọkan ka si ọmọ- nikeji gẹgẹ bi a ti se n tujuka sii.
Ki a ma korira eniyan ẹgbẹ wa tabi fi oju yẹpẹrẹ rẹ tabi isẹ ti o ba n se, ni iwọn igba ti ko ba ti se ohun ti Ọlọhun ati Annabi rẹ kọ fun wa.
Ki a mojuto okun ti o sowa papọ ki o ma baa ja. Nitoripe ọpọlọpọ igba ni ẹ
o ma ri ti awọn eniyan yoo maa wipe lagbaja sọ bayi, tamodo gbero nkan bayi. Bi a ko ba ni erongba daada si ara wa awọn nkan wonyii ni wọn yoo ge okun ti o sowa papọ, yoo si da isoro ati wahala silẹ lawujọ.
ọpọlopọ awọn awujọ ti o fọ loni jẹ esi erongba ti o buru ti wọn n ro si arawọn. Nini ni ero buburu si ẹnikeji ẹni, maa n fa ikorira. Bakannaa kii jẹ ki a le fi ọkan balẹ le ara ẹni lori.
Nini ero buburu si ara ẹni yoo se okunfa ki agbara-wa ati isọkan-wa lọ, ti a ko si ni le bori ogun lailai. Oluwa ni:
وَأَطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَلَا تَنَازَعُوا فَتَفْشَلُوا وَتَذْهَبَ رِيحُكُمْ وَاصْبِرُوا إِنَّ اللَّهَ مَعَ الصَّابِرِين
Ẹ tẹle Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ, ẹ ma se ariyanjiyan, ki ẹ ma baa kọlẹ tabi se ojo, ki agbara yin o ma baa lọ. Atiwipe ki ẹni agbamọra (suuru), dajudaju Ọlọhun nbẹ pẹlu awọn oni-suuru.
Ero buruku ko ni mu oriire wa ayafi ikorira, ọta sise ati fifọnka yẹlẹyẹlẹ, bakannaa yoo se okunfa ki ijẹ ọmọ-iya ẹsin di ohun igbagbe.
Ẹwẹ ero buruku yoo sọ olowo rẹ sinu ẹsẹ miran bẹẹ ni yoo wa ninu awọn ti wọn yoo kabamọ ti o ba di ọjọ ẹsan.
Iwa buruku yoo jẹ ki ẹni ti wọn hu u si gba okun ni ọdọ Oluwa. Eleyi ni yoo se okunfa Alujanna fun wọn ti awọn ti wọn n fi wọn se yẹyẹ yoo si pada di ọmọ-ina. Oluwa wipe:
{إِنَّ الَّذِينَ أَجْرَمُوا كَانُوا مِنَ الَّذِينَ آَمَنُوا يَضْحَكُونَ (29) وَإِذَا مَرُّوا بِهِمْ يَتَغَامَزُون}.
"Dajudaju awon ẹniti wọn n dẹsẹ, wọn tun nbẹ ninu awọn ti nfi awọn onigbagbọ rẹrin. Nigbati nwọn ba nkọja lọ lara wọn, wọn o ma sẹju si ara wọn (wọn o maa fi ọwọ tọ ara wọn)…Suratu Mutọfifina-83
Oluwa tun sọ pe:
فَالْيَوْمَ الَّذِينَ آمَنُوا مِنَ الْكُفَّارِ يَضْحَكُون [المطففين : 34]
"Sugbọn loni awọn onigbagbọ ododo ni nwọn o maa fi awọn alaigbagbọ rẹrin".
Oluwa sọ ninu Suratul Bakọrah pe:
زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَيَسْخَرُونَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا وَالَّذِينَ اتَّقَوْا فَوْقَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ وَاللَّهُ يَرْزُقُ مَنْ يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَاب [البقرة : 212]
"A se ile aiye ni ohun ti yoo ma a jọ awọn ti ko gbagbọ l’oju, (nipa bayi) awọn a ma fi awọn onigbagbọ se ẹfẹ. Sugbọn awọn ti wọn bẹru Ọlọhun, yio juwọn lọ (nipa ikẹ Ọlọhun) ni ọjọ ikẹhin Ọlọhun A maa se arisiki fun ẹni ti O ba fẹ lai ni osun-wọn.
· Oluwa tun ni:
{يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آَمَنُوا اجْتَنِبُوا كَثِيرًا مِنَ الظَّنِّ إِنَّ بَعْضَ الظَّنِّ إِثْمٌ وَلَا تَجَسَّسُوا وَلَا يَغْتَبْ بَعْضُكُمْ بَعْضًا أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ أَنْ يَأْكُلَ لَحْمَ أَخِيهِ مَيْتًا فَكَرِهْتُمُوهُ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ تَوَّابٌ رَحِيم}.
"Ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ jinna si ọpọlọpọ erokero, dajudaju apakan erokero (abadida) jẹ ẹsẹ. Ki ẹ si ma se maa fi imu finlẹ wadi laifi araayin, ki ẹ si ma se maa sọ ọrọ araa yin lẹhin pẹlu. Njẹ o ha le wu ẹnikan ninu yin ki o maa jẹ ẹran ara ọmọ iya rẹ ti o ti ku bi? Ẹyin korira lati se bẹẹ. Atipe ki ẹ bẹru Ọlohun, Daju-daju Ọlohun naa jẹ Olugba ironupiwada lọpọlọpọ Alaanu julọ".
Awọn aaya yii n tọka si fun wa pe ki a maa sọ orukọ musulumi kuro nibi ibajẹ ki a si maa se iwadi ohun gbogbo siwaju ki a to le sọ pe lagbaja ni o sọ pe.
Itaniji ni eyi jẹ fun gbogbo muslumi, torinaa ki a gbe ju silẹ ohun ti o ba le se akoba fun enikan nipa èrò buruku.
· Anaabi (صلى الله عليه وسلم) sọ ninu Hadiisi . Abu Hurairah sọ pe: ẹ sọra fun abadida (mo ro pe lagbaja se nkan bayi …ati bẹẹ bẹẹ lọ), nitoripe abadida jẹ ọga fun irọ.
· Ofin pawa lasẹ pe ki a jinna si gbogbo ohun ti o ba sokunkun siwa ti a ko ni imọ nipa rẹ lati ma sọ.
· Ẹni apọnle ni ẹni ti o pa ọkan lofo kuro nibi riro erokero si muslumi ẹgbẹ rẹ.
· Ninu eroburuku ni gbigbe ọrọ ẹlomiran lati aayekan si ekeji ni aniyan lati ba ẹnikeji jẹ lai-si ẹri ti o fẹsẹ mulẹ lori ẹsun ti a fi kan ẹni naa.
· Ninu ẹkọ ẹsin nipe ki a maa sọ nipa eniyan kan ayaafi ohun ti a ba mọ nipa rẹ.
· Ummar (ki Ọlohun yọnu si) sọ ninu Hadiisi Utba bun Mos’ood pe: waayi ni o maa n se ofofo awọn eniyan ni igba aiye Annabi, sugbọn ni iwọn ìgbà ti ko ti si mọ, ki a maa se idajọ lori ohun ti o ba han siwa loku. Ẹniti o ba fi daada han siwa a o fi ọkan tan-an, a o ni bukata si kọkọ rẹ. oluwa yoo se idajọ kọkọ rẹ,
· Musulumi si gbọdọ se akiyesi iru gbolohun ti yoo ba maa fi ẹnu rẹ sọ nitoripe Oluwa wipe:
وَلَا تَقْفُ مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ إِنَّ السَّمْعَ وَالْبَصَرَ وَالْفُؤَادَ كُلُّ أُولَئِكَ كَانَ عَنْهُ مَسْئُولًا
« Iwọ ma se sọ ohun ti o ko ba ni imọ nipa rẹ, nitoripe igbọran, iriran ati ọkan ni A o beere nipa wọn ».
Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, awọn ohun ti o maa n fa ki eniyan maa ro ero buruku, pọ ninu rẹ ni ; kojẹpe eniyan jẹ eeyan’buru, tabi ki o wulẹ ni ẹmi buruku.
· Ti eniyan ba ti n te le ifẹ-inu rẹ ko si bi ko se nii maa ro eroburuku, nitori ẹmi ko ni asẹ kan ti n paa, ju asẹ buruku lọ. Nitorinaa eniyan gbọdọ jinna si ifẹ-inu.
· Bi eniyan ba korira alasunmọ rẹ kan, ko si ọgbon, ero buruku ni yoo maa ro si irufẹ ẹni bẹẹ.
· Ohun ti o tun ma n fa eroburuku ni ki ẹnikan ri ara rẹ lori ododo ki o si ri awọn yoku ni opurọ tabi ki o ma ni ero pe oun daa ju awọn ara yoku lọ.
· Mimọọ gbero buruku nipa musulumi ti di ohun ti o kari ni akoko ti a wa yii. Eleyi yoo si pada se okunfa wahala ti o tobi ni awujọ ẹsin.
Oluwa sọ wipe:
وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا [الأحزاب : 58]
"Awọn ẹni ti nko inira ba awọn olugbagbọ lọkunrin ati obirin (pẹlu ọrọ tabi iwa) lori ohun ti wọn ko se, wọn ti pa irọ (nla) wọn si da ẹsẹ ti o foju han gbangba".
Ki a lọ mọ pe, eroburuku jẹ okunfa iparun atipe a gbọdọ se itọju ẹmi wa kuro ni bi aisan yii, ki a le ẹmi araawa kuro nibi iparun.
Awọn ọna ti a fi le tọju ẹmi ara wa ni pe ki a maa gbiyanju lati maa ro daradara si araawa ki a si jinna si mimaa sọ kọkọ onikọkọ.
Bẹẹni ki a dunnimọ awon ẹkọ ẹsin daadaa.
فاتقوا الله - عباد الله – واجتنبوا إساء الظن بإخوانكم المسلمين وتفطّنوا أن هذا من مكائد الشيطان اللعين ثم اعلموا أن الله سبحانه أمرني وإيّاكم بأمر بدأ به بنفسه الكريمة وملائكته الكرام. قال عزّىمن قائل: {إن الله وملائكته يصلون على النبي يأيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلّموا تسليما}
اللهم صل وسلم على عبدك ونبيك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر وعمر وعثمان وعلي وعن سائر أصحابه وعنا معهم برحمتك يا أرحم الراحمين. اللهم أعزّ الاسلام.
Ẹ bẹru Ọlọhun –ẹyin ẹrusin Ọlọhun - Ẹ jinna si erokero si awọn ọmọ iya yin Musulumi, ki ẹ si lọọ mọ pe erokero ninu ète esu ni, atipe Ọlọhun kọọ fun wa.
Ẹ lọọ mọ pe dajudaju Ọlọhun pawa lase sise Asalatu fun Annabi r
eyi ti o bẹrẹ lati ori ara rẹ ati awọn Malaika Rẹ,
Ọlọhun bawa se ikẹ se igẹ fun Ojisẹ nla Anabi Muhammad, ki o si bani yọnu si awọn arole rẹ latori Abu bakr, Umar, Usman, Ali ati gbogbo awọn Sahabe latoke delẹ ati gbogbo awa olutẹle- wọn di ọjọ igbende Alukiyaomo. Ọlọhun bani ro Isilaamu lagbara.