islamkingdomfacebook


AYẸYẸ ỌDUN TUNTUN

AYẸYẸ ỌDUN TUNTUN

4058
Eko ni soki
Bi ojo ti nbori ojo ni odun naa nbori odun, o wa ninu awon omoniyan, eniti o nlekun ni asumo Olohun, o si wa ninu won eniti o nlekun ni ijinna si Olohun, gbogbo odun ti o nrekoja lori eniyan ni yio jeri takoo tabi ki o jeri gbee, onilakai ni eniti o koro ojo ori re, ti o si se anfaani pelu awon asiko re nibi iwa iyonu Olohun ti ola re ga ati ise tooto ti o nso eso ti o se anfaani fun esin ati awujo re.

 


Awọn erongba khutuba:

1-        Idagbere fun ọdun to ti nlọ ati igbaradi fun ọdun tuntun.

2-        Imuki aarin eniyan kó dàra gan an ninu gbogbo isesi ninu odun to nbọ yii.

3-        Iseni loju ọyin nipa pipese nkan jade ati isẹ sise

            Akoko kutuba: isẹju marindinlogoji

Khutuba alakoko: iseju metadinlogun

الحمد لله  ذي الفضل والاحسان  شرع لعباده  هجرة القلوب وهجرة الأبدان. وجعل هاتين الهجرتين  باقتين على مرّ الزّمان  وأشهد أن لاإله إلا الله وحده لا شريك له في ربوبيّته وإلهيّته وأسمائه وصفاته الحسان , وأشهد ان محمدا عبده ورسوله , أرسله بالهدي ودين الحق ليظهره على سائر الأديان . صلّ الله عليه وعل آله وأصحابه الذين هاجر وا وجاهدوا حتى فتحوا القلوب والأبدان , ونشروا العدل والأمن والإيمان سلم تسليم كثيرا. أما بعد

A dupẹ fun Ọlọhun ọba ti o sẹ wa ku ti a fi ri ọdun tuntun. A jẹri pe ko si ẹlomiran ti isin ododo tọ si ayafi Ọlọhun nikan, ko lorogun, ko lẹgbẹra bẹni A jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni ojisẹ Rẹ si ni pẹlu, ikẹ Ọlọhun ati igẹ Rẹ ki o maa baa, ati awọn ara ile rẹ ati awọn sahabe rẹ, ati gbogbo ẹlẹsin isilaamu lapapọ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ọpọ ẹda lo ti fọnu fọra ti ko furamọ pe aye yii ntara yipo latari; ohun ti o ntanma lati da laye. Afa asani sọ pe: Ẹ sọra fun mimọọ tanmọọ, toripe titanmọọ koni ki eniyan ri ohun ti o nwa laye ati lọrun”. Ahmọdu lo gbaa wa.

"أَوَلاَ يَرَوْنَ أَنَّهُمْ يُفْتَنُونَ فِي كُلِّ عَامٍ مَّرَّةً أَوْ مَرَّتَيْنِ ثُمَّ لاَ يَتُوبُونَ وَلاَ هُمْ يَذَّكَّرُون".

Ọlọhun sọ pe: "Abi awọn naa ko ha mọ pe a ndan wọn wo ni  ẹẹkan tabi ẹẹmeji ni ọdọọdun, lẹhinnaa nwon ko ronupiwada, bẹẹ si ni nwọn ko nse iranti” suratul taobah:126.

Afa Mujahidu sọ pe- Ọlọhun yoo maa fi ọda ati ebi dan wọn wo”. Afa wa kọtadatu sọ pe: Wọn yoo fi iyan dan wọn wo lẹẹkan tabi ẹẹmẹji lọdun. Afa wa Atiyyatu sọ pe: “Awọn àrùn ati ẹtaẹro ni wọn yoo fi dan wọn wo”.

                        Awọn sahabe ojisẹ Ọlọhun jẹ ẹniti o maa nwa awọn eniyan nisọra kuro nibi igbagbe ati isasun-piye. Afa wa Fudọelu bere lọwọ arakunrin kan pe: ọmọ ọdun melo ni ọ? O dahun pe: ọmọ ọgọta ọdun ni oun. Afa Fudọelu sọ pe: o di ọgọta ọdun loni ti o ti nlọ pade Ọlọhun rẹ, o ku diẹ ti ẹ o pade.

Nitori naa o yẹ ki kaluku maa bi ara rẹ leere pe: irun melo ni mo ra lare, jimoh melo ni mo padanu, njẹ mo gbawẹ ọdun yii pe, se mo yọ  saka tọdun yii bi, tabi mo se ahun? Daada melo ni mo se tabi ti mo pa awọn eniyan lasẹ rẹ? Aidara wo ni mo se tabi ti wọn nse loju mi sugbọn ti n o kọọ fun awọn ti wọn nse e, ọrọ alufansa melo lo jade lenu mi, ọrọ ẹhin nkọ, ẹẹmelo ni mo yọ òbí mi ninu tabi dùnwọn nínú, eeyan melo ni mo  yànjẹ tabi bòsí ọrọ ẹhin nkọ ofofo naa ko ma gbehin.

قال تعالى: "يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اتَّقُوا اللَّهَ وَلْتَنْظُرْ نَفْسٌ مَا قَدَّمَتْ لِغَدٍ وَاتَّقُوا اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ (18) وَلا تَكُونُوا كَالَّذِينَ نَسُوا اللَّهَ فَأَنْسَاهُمْ أَنْفُسَهُمْ أُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُون".

Ọlọhun sọ pe: "Ẹyin ẹniti ẹ gbagbọ ododo ẹ paya Ọlọhun ati ki ẹmi kọkan maa woye ohun ti o nti siwaju fun ọla, atipe ki ẹ bẹru Ọlọhun. Dajudaju Ọlọhun naa ni alamọtan ohun ti ẹ nse nisẹ. Atipe ki ẹ mase da gẹgẹ bi awọn ẹniti nwọn gbagbe Ọlọhun ti Ọlọhun si mun won gbagbe ori ara won” Suratul Hasri: 18-19.

Ọlọhun tun sọ pe : “Ni ọjọ  ti ẹmi kọọkan yoo ri aridaju ohun ti o se ni rere ati eyiti o se ni aburu (ni ọdọ ara rẹ ), yoo fẹ pe ki orere ti o jinna ma bẹ ni arin on ati isẹ buburu rẹ, suratu al-imran: 30 Umaru bun Khatọbi sọ pe: “Ẹ siro ẹmi ara yin siwaju ki wọn to bayin sii, ẹ wọn ẹmi ara yin wo, siwaju ki wọn to bayin wọn ọn, ẹ se ọsọ silẹ de ọjọ ti wọn yoo sẹri yin lo sibi isiro “Ni ọjọ naa a o seri nyin (si isiro isẹ), ko ni si asiri nyin kan ti yoo pamọ”    

Gunaemu bunu Kọesi sọ pe: A maa nfi nkan mẹrin kan se waasi fun ara wa nigba ti isilaamu sẹsẹ gbilẹ: Si sesẹ silẹ nigba ọdọ di igba ogbó, ni igba ti o raaye di igbati o o káìrójú, ni ìgbà alafia de igba aarẹ, nigbati o nsemi lọwọ de igbati o o ku Ahmọdu lo gba wa ninu súhúdù.

 

 

Afa wa ibnul Kọyyimu sẹ alaye nipa bi a sele sẹ isiro ẹmi ẹni o ni:

1.         A o bẹre pẹlu awọn ọranyan, njẹ o se e lasepe bi, bi koba pe tete wa bi yoo se pe.

2-        Awọn ohun ti Ọlọhun kọ, ti o ba ri pe o ti se ọkan ninu rẹ tete yara tuba, tọrọ aforijin ki o si maa se daada ki Ọlọhun le fii parẹ

3-        Ifonu fọra nipa iranti Ọlọhun, òògùnrẹ ni iranti Ọlọhun ati sisẹri pada si ọdọ Rẹ.

4-        Lilọ bibọ orike ara, kini o fi ẹnu da lẹsẹ, ibi isẹ ẹsẹ wo ni o fi ẹsẹ rin lọ? ẹsẹ wo ni o fi ọwọ rẹ da tabi ti o fi oju da, kini o si fi ẹti rẹ da lẹsẹ. Musulumi gbọdo jinna si awọn adadasilẹ ijọsin ti awọn eniyan maa nda ni ipari ọdun, ninu rẹ ni, asikiri ti ko ni ipilẹ. Ni ipari, afa wa Usman bunu Foodi sọ pe: Ẹniti o ba fẹ ki Ọlọhun tan imọlẹ sinu ọkan oun ki o se nkan mẹrin:

{i}       kiko airoju pẹlu ibẹru Ọlọhun, pelu titẹlẹ asẹ Rẹ, ati jijinna si ohun ti O kọ

{ii}-    Kike Alkur’an                      

{iii}    Kikairoju pẹlu kika ati gbigbọye adisi anọbi, ati itan rẹ

{iv}     Kika itan awon ẹni isiwaju.’

 

Ni ipari, ibẹru Ọlọhun dọwọ tolori tẹlẹmu wa, ki ẹ si lekun ni isẹ rere ati iwa rere ninu ọdun tuntun yii, bọya ninu ọdun yii ni asiko ati bỌlọhun wa pade yoo jẹ, a o mọ, nitorinaa, ẹ maa sin Ọlọhun bii pe ẹ n ri I, toripe bi ẹyin ko ba ri I, dajudaju Ọlọhun nri yin, ki Ọlọhun sewa loloriire laye ati lalukiyamọ.

 

فاتقوا الله عباد الله واقتبسوا من الهجرة وغيرها من أحداث السيرة النبوية  دروسا  تنهجونها في حياتكم.  نسأل الله أن يتوفنا مسلمين ويلحقنا  بالصالحين وصلّى الله على سيدنا محمد وعلى آله وصحبه أجمعين