islamkingdomfacebook


Ọdún Ìtunu awẹ

Ọdún Ìtunu awẹ

17360
Eko ni soki
Odun itunu aawe je okan ninu odun meji ti Olohun Oba Alekeola se ni eto fun awa musulumi lati fi maa dupe oore re ti a o le ka tan lewa lori lati ara iroro igba aawe osu nla(osu Ramadan) ati sise awon oniranran ijosin fun-un ninu re ni irorun.

 

(Idul fitri)

Awọn erongba Khutuba:

1.         Alaye nipa pe dídúpẹ, fifẹyin fọlọhun lara erongba ọdun ni

2.         Riranra ẹni lọwọ ati sise daada sawọn to nbukata.

3.         Sise afihan awọn ámìn isilaamu lọjọ ọdun

 

الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر. الله أكبر كبيرا, والحمد لله كثيرا , وسبحان الله بكرة وأصيلا. الحمد لله الذي سهّل لعباده طريق العبادة ويسّر  , وجعل لهم عيدا يعود عليهم فضله  الذي لايحصر, فما انقضى شهر الصيام إلا وأعقبه بأشهر الحجّ إلى بيته المطهّر,  أحمده وهو أحق أن يحمد ويشكر, وأمشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له شهادة  تنجي من قالها وعمل بمقتضاها يوم الفزع الأكبر , ,أشهد أن محمدا عبده ورسوله  صاحب المقام المحمود والكوثر , صلّى الله عليه  وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما  كثيرا إلى يوم البعث والمحشر. أما بعد/

Allọhu Akbar, Ọlọhun tobi (9ce) Ọlọhun tobi pupọ o, A dupe fun Ọlọhun lọpọpọlọpọ, mimọ ni fỌlọhun lowurọ ati àsálẹ. A dupẹ, fỌlọhun to se mimaa sin in nirọrun fun awọn ẹru Rẹ, O tun jẹ ki a peju pesẹ loni ọdun, lẹhin awọn ọjọ ti a ti fi gba awẹ, ọgọrọ ẹda la dijọ bẹrẹ awẹ ti wọn ti se alaisi omiran mbẹ nile iwosan, ti wọn o mọ bi yoo ku tabi yoo yè. Mo jẹri pe ko si ẹniti isin ododo tọ si ayafi Ọlọhun nikan, ko lorogun, bẹni mo si jẹ ri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni ojisẹ Rẹ si ni. Ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa baa ati awọn ara ile rẹ ati awọn sahabe rẹ titi di ọjọ akojọ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun o tọ ki a dupẹ fọlọhun lori pe o jẹ ki ẹmi wa ri ipari awẹ rọmọdana.

قال تعالى: { شَهْرُ رَمَضَانَ الَّذِي أُنْزِلَ فِيهِ الْقُرْآنُ هُدًى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَاتٍ مِّنَ الْهُدَى وَالْفُرْقَانِ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ الشَّهْرَ فَلْيَصُمْهُ وَمَن كَانَ مَرِيضاً أَوْ عَلَى سَفَرٍ فَعِدَّةٌ مِّنْ أَيَّامٍ أُخَرَ يُرِيدُ اللَّهُ بِكُمُ الْيُسْرَ وَلاَ يُرِيدُ بِكُمُ الْعُسْرَ وَلِتُكْمِلُواْ الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُواْ اللَّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ وَلَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ }.

 Ọlọhun sọ pe: "Osu Ramadhan ni eyiti a sọ al-kur’an kalẹ ninu rẹ, ilana ni o jẹ fun awọn enia ati ẹri ododo ti ilana - otitọ na ati ipinya (ododo pẹlu irọ) nitorinaa,, ẹnikan ti osu naa ba se oju rẹ ninu nyin, njẹ ki o gba awẹ ninu rẹ, ẹniti o ba n se aisan tabi o mbẹ lori irin ajo (yoo san awẹ na pada ninu) onka awọn ọjọ miran. Ọlọhun nfẹ irọrun pẹlu nyin ko si fẹ inira fun nyin, ki ẹ si se asepe onka naa ki ẹ ba le se agbega fun (orukọ) Ọlọhun nitori ọna ti O fi mọ nyin ati ki ẹnyin le ma se ọpẹ” Suratul Bakọrah: 185.

Umaru bunu Khatọbi sọ pe: Ọjọ mejeeji yii, ojisẹ Ọlọhun se gbigba awẹ leewọ ninu wọn: Ọjọ itunu yin ninu awẹ yin, ikeji, ọjọ ti ẹ o jẹ ninu ẹran ijọsin yin” Buhari ati Msulim lo gbaa wa. Anọsi sọ pe; Annọbi de ilu mọdina o si ba awọn ara ibẹ ti wọn ya ọjọ meji silẹ fun eré sise, o si sọ fun wọn pe: Ọlọhun ti fi ọjọ meji to lore ju wọn lọ rọpo wọn: ọjọ ileya ati ọjọ itunu awẹ “Abu Daud ati Nosai lo gba a wa. Ummu Atiyyati sọ pe: Wọn pawa lase ki gbogbo wa jade loojọ ọdun, a si nmun ọlọmọge jade labẹ àbò rẹ, to fi dori obinrin to nse nkan osu lọwọ, awọn yoo to sẹyin awọn eniyan (olukirun) wọn yoo maa se “Allọhu Akbaru” pẹlu awọn olukirun, bẹẹni wọn o maa se adua bi wọn ba ti n se adua, wọn nse agbenle alubarika ọjọ naa, ati imọra rẹ”. Buhari lo gba wa.

Ọjọ ọsọ, igbaradi ati ise irọrun fun awọn ara ile ẹni. Umaru mun asọ gbagẹrẹ kan ti wọn se lati ibi alaari ti wọn nta lọja wa sọdọ ojisẹ Ọlọhun, o si sọ pe: ra asọ yii, irẹ ojisẹ Ọlọhun, ki o maa fi se ọsọ fun ọdun ati fun awọn alejo ti o ba wa ba ọ”. Buhari lo gba a wa. Ọjọ yii tun jẹ ọjọ ti a maa nyọ jaka. Abdullọhi bunu Abasi sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun se yiyọ jaka lòranyàn, ti yoo maa jẹ afọmọ fun alaawẹ kuro nibi ọrọ ti ko ni anfani ati ọrọ isọkusọ ati onjẹ fun awọn alaini, ẹniti o ba yọọ siwaju irun yidi, lo yọ jaka ti Ọlọhun yoo tẹwọ gba, ẹniti o ba yọọ lẹhin rẹ, bi ẹniti o se saara kan ninu awọn saara ni: ọjọ ti a maa nse “Allọhu akbaru” (Ọlọhun  tobi julọ) ni. Wo suratul Bakọrah: 185.

Abdullọhi bunu Umar sọ pe: Ojise Ọlọhun jẹ ẹniti o maa ngbe Ọlọhun  tobi nigbati o ba n lọ si ibukirun loojọ ọdun”. Fariyabi lo gba a wa.

 

 

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , ẹ lọ mọ pe irun yidi raka meji pere ni, a kii yan nọfila kan kan siwaju tabi lẹhin rẹ, ni ibamu si adisi Abdullọhi bunu Abasi ti Buhari gba a wa. Irun ni a o kọkọ ki siwaju ki a to se khutubah ni ibamu si adisi Abdullọhi bunu Abasi bakanna. Ninu ẹgbawa ọrọ miran ẹwẹ, ojisẹ Ọlọhun  wa si ọdọ awọn obinrin, atohun ati Bilalu, o si pawọn lase saara sise, ni wọn ba bere sini da nkan ọrun ati teti jọ” Buhari lo gba a wa. Ninu ẹgbawa ọrọ miran to jẹ ti Abu Daud “ o si pin in laarin awọn alaini musulumi” Afusọtu ọmọ siirin sọ pe: A jẹ ẹniti o ma nkọ fun awọn ẹru-binrin wa lati jade lọjọ ọdun, lobinrin kan ba de, lo ba wọ aafin bani Khalafi, ni wọn ba lọọ baa nibẹ, o si sọ fun wọn pe: ọkọ ọmọ iya oun lobinrin jagun lẹẹmejila pẹlu ojisẹ Ọlọhun, ọmọ iya oun si kopa nibi mẹfa ninu rẹ, o sọ pe: A jẹ ẹniti o maa nse amojuto fun awọn ti ara wọn ko yá, bẹẹni a si n lo oogun fun awọn ti wọn sa lọgbẹ, awọn wa bere pe irẹ ojisẹ Ọlọhun, njẹ aburu wa nibi kẹ enikan ninu wa ti ko ni jalibaba saláì lọ si yidi bi? Ojisẹ Ọlọhun daa lohun pe: ki ọrẹ rẹ binrin fun un wọ ninu jalibaba rẹ, ki wọn le lanfani lati foju gan an ni ore ati adua awọn onigbagbọ ododo”. Buhari lo gba a wa.

Kódà ọjọ ti a maa nse abẹwo ara ẹni ni, ni ibamu si adisi Aisat. O dara pupọ bi musulumi ba le gba awẹ ọjọ mefa sii ninu osu sawali. Ninu adisi Abu Ayyuubulal’ansọri, o sọ pe: Dajudaju ojisẹ Ọlọhun  sọ pe: Ẹniti o ba gba awẹ rọmadan tan, lẹhinna ti o fi awẹ ọjọ mẹfa miran tẹ lee ninu osu Sawali, yoo dabi ẹniti o fi gbogbo igbesi aye rẹ gbawẹ”. Musilimu lo gba a wa.

Ni ipari, ẹ jẹ ẹniti yoo maa da ọpẹ fun Ọlọhun ni gbogbo ìgbà,

قال تعالى: "وَاشْكُرُواْ اللَّهِ إِن كُنْتُمْ إِيَّاهُ تَعْبُدُونَ".

 Ọlọhun sọ pe "ki ẹ si ma dupẹ fun Ọlọhun ti o ba jẹ pe On ni ẹnyin nsin”. Suratul Bakọrah: 172.

Ọlọhun tun sọ pe:

"وإذ تأذّن ربّكم لئن شكرتم لأزيدنّكم ولئن كفرتم إنّ عذابي لشديد"

“Atipe nigbati Oluwa nyin jẹ ki ẹ mo pe, dajudaju ti ẹnyin ba dupẹ, dajudaju emi yoo se alekun fun nyin, sugbọn ti ẹnyin ba se aimore, ( ẹ mọ pe) dajudaju ìyà Mi le koko”. Suratul Ibrohim: 7

Umran bunu Usaeni sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Ẹniti Ọlọhun ba se idẹra kan fun dajudaju Ọlọhun yoo nifẹ si ki o ri oripa idẹra Rẹ lori ẹru bẹẹ”.

Ni ipari, ẹ bẹru Ọlọhun, ẹ fi pipejọ yin toni ranti ọjọ akojọ lọjọ alukiyamọ ni ọjọ ti Ọlọhun yoo kowajọ saaye kan ti ẹda yoo pin si ọna meji: Oloriire ati olori buruku. Nitorinaa, ẹ jẹ ki a mura si isẹ rere ni sise. Ẹ lọ ọ mọ pe ọrọ Ọlọhun lo loore julọ, ilana Annọbi lo si dara julo, adadaalẹ si buru jọjọ, torinaa, ẹ jinna sii, ki ẹ si pọ lẹniti yoo maa tọrọ ikẹ ati igẹ fun Annọbi wa gẹgẹ bi Ọlọhun se pasẹ rẹ, bẹẹ ni ki ẹ maa tọrọ iyọnu Ọlọhun fun awọn arole mẹrẹẹrin: Abu Bakri, Umar, Usman ati Aliyu ati awọn sahabe yo ku naa. Ọlọhun ba wa gbe asọ agbara wọ awọn musulumi lọrun, ma yẹpẹrẹ wa, ma yẹpẹrẹ ẹsin wa, jẹ ka niyi laye ati lọrun, ma se odun yii ni asemọ fun wa, salekun imani ati ibẹru Ọlọhun fun wa.

فاتقوا الله -  عباد الله وتذكروا باجتماعكم  هذا لإجتماع الأكبر  على أرض المحشر :   واعلموا أن خير الحديث كتاب الله , وخيرا الهدي  هدي محمد صلّى الله عليه وسلم وشرّ الأمور محدثاتها  وعليكم بالجماعة  فإن  يد الله على الجماعة  ومن شذّ شذّ في النّار  إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليما اللهم صلّ عل عبدك ورسولك نبينا محمد وارض اللهم عن خلفائه الراشدين . أبي بكر وعمر  وعثمان وعلي  وعن الصحابة  أجمعين  اللهم أعزّ الإسلام والملمين ودمّر أعداء الدين اللهم اجعل هذا البلد آمنا مطمئنا  وسائر بلاد المسلمين  عامة يارب العالمين.